OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ rú ẹbọ alaafia sí OLUWA, yóo mú ẹbọ náà wá fún OLUWA. Ninu ẹbọ alaafia rẹ̀, ni yóo ti fi ọwọ́ ara rẹ̀ mú ẹbọ sísun wá fún OLUWA. Ọ̀rá ẹran náà pẹlu àyà rẹ̀ ni yóo mú wá. Alufaa yóo fi àyà ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú OLUWA. Alufaa yóo sun ọ̀rá ẹran náà lórí pẹpẹ, ṣugbọn àyà rẹ̀ yóo jẹ́ ti Aaroni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ óo fún alufaa ní itan ọ̀tún rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ lára ẹbọ alaafia yín. Èyíkéyìí ninu àwọn ọmọ Aaroni tí ó bá fi ẹ̀jẹ̀ ati ọ̀rá ẹran náà rúbọ ni ó ni itan ọ̀tún ẹran náà gẹ́gẹ́ bí ìpín tirẹ̀. Nítorí mo ti gba àyà tí a fì ati itan tí a fi rúbọ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli lára ọrẹ ẹbọ alaafia wọn, yóo sì jẹ́ ti Aaroni, alufaa, ati àwọn ọmọ rẹ̀. Èyí ni ìpín tiwọn láti ọ̀dọ̀ àwọn eniyan Israẹli. Ìpín Aaroni ni ati ti àwọn ọmọ rẹ̀, lára ẹbọ sísun tí a rú sí OLUWA, àní ẹbọ tí a yà sọ́tọ̀ fún wọn, ní ọjọ́ tí a mú wọn wá siwaju OLUWA láti máa ṣe iṣẹ́ alufaa. Ní ọjọ́ tí a fi òróró yàn wọ́n, ni OLUWA ti pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti máa fún wọn, ó jẹ́ ìpín tiwọn láti ìrandíran.” Òfin ẹbọ sísun ni, ati ti ẹbọ ohun jíjẹ, ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀, ati ti ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, ti ẹbọ ìyàsímímọ́, ati ti ẹbọ alaafia; tí OLUWA paláṣẹ fún Mose, ní orí òkè Sinai ní ọjọ́ tí ó pàṣẹ fún àwọn eniyan Israẹli láti mú ẹbọ wọn wá fún òun OLUWA ninu aṣálẹ̀ Sinai.
Kà LEFITIKU 7
Pín
Fi gbogbo Èyá wéra: LEFITIKU 7:28-38
Ṣe àfipamọ́ àwọn ẹsẹ, kàá ní aìsìní orí ayélujára, wo àwọn àgékúrú ìkọ́ni, àti díẹ̀ síi!
Ilé
Bíbélì
Àwon ètò
Àwon Fídíò