Ẹk. Jer 3:37-50
Ẹk. Jer 3:37-50 Bibeli Mimọ (YBCV)
Tali ẹniti iwi, ti isi iṣẹ, nigbati Oluwa kò paṣẹ rẹ̀. Ibi ati rere kò ha njade lati ẹnu Ọga-ogo-julọ wá? Ẽṣe ti enia alãye nkùn? ti o wà lãye, ki olukuluku ki o kùn nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀! Jẹ ki a wádi, ki a si dán ọ̀na wa wò, ki a si tun yipada si Oluwa. Jẹ ki a gbe ọkàn ati ọwọ wa soke si Ọlọrun li ọrun. Awa ti dẹṣẹ, a si ti ṣọtẹ: iwọ kò ti dariji. Iwọ ti fi ibinu bora, o si ṣe inunibini si wa: iwọ ti pa, o kò si ti dasi. Iwọ ti fi awọsanma bo ara rẹ, ki adura má le là kọja. Iwọ ti ṣe wa bi idarọ ati ohun alainilãri li ãrin awọn orilẹ-ède. Gbogbo awọn ọta wa ti ya ẹnu wọn si wa. Ẹ̀ru ati ọ̀fin wá sori wa, idahoro ati iparun. Oju mi fi odò omi ṣan silẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi. Oju mi dà silẹ ni omije, kò si dá, laiṣe isimi. Titi Oluwa fi wò ilẹ, ti o wò lati ọrun wá
Ẹk. Jer 3:37-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀ tí Olúwa kò bá fi àṣẹ sí i. Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá-ògo jùlọ ni rere àti búburú tí ń wá? Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè ṣe ń kùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa, kí a sì dán an wò, kí a sì tọ OLúWA lọ. Ẹ jẹ́ kí a gbé ọkàn àti ọwọ́ wa sókè sí Ọlọ́run ní ọ̀run, kí a wí pé: “Àwa ti ṣẹ̀ a sì ti ṣọ̀tẹ̀ ìwọ kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. “Ìwọ fi ìbínú bo ara rẹ ìwọ sì ń lépa wa; ìwọ ń parun láìsí àánú. Ìwọ ti fi àwọsánmọ̀ bo ara rẹ pé kí àdúrà wa má ba à dé ọ̀dọ̀ rẹ. Ó ti sọ wá di èérí àti ààtàn láàrín orílẹ̀-èdè gbogbo. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọn gbòòrò sí wa. Àwa ti jìyà àti ìparun, nínú ìbẹ̀rù àti ewu.” Omijé ń sàn ní ojú mi bí odò nítorí a pa àwọn ènìyàn mi run. Ojú mi kò dá fún omijé, láì sinmi, títí ìgbà tí OLúWA yóò ṣíjú wolẹ̀ láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.
Ẹk. Jer 3:37-50 Yoruba Bible (YCE)
Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i? Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògo ni rere ati burúkú ti ń jáde? Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò, kí á tún ọ̀nà wa ṣe, kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA. Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè, kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run: “A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun, ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá. “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù, ò ń lépa wa, o sì ń pa wá láì ṣàánú wa. O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ. O ti sọ wá di ààtàn ati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára. Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa. Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi, nítorí ìparun àwọn eniyan mi. “Omijé yóo máa dà pòròpòrò lójú mi láì dáwọ́ dúró, ati láìsinmi. Títí OLUWA yóo fi bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, tí yóo sì rí wa.