ẸKÚN JEREMAYA 3:37-50

ẸKÚN JEREMAYA 3:37-50 YCE

Ta ló pàṣẹ nǹkankan rí tí ó sì rí bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé OLUWA ló fi ọwọ́ sí i? Àbí kì í ṣe láti ẹnu Ọ̀gá Ògo ni rere ati burúkú ti ń jáde? Kí ló dé tí ẹ̀dá alààyè kan yóo fi máa ráhùn nígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀? Ẹ jẹ́ kí á yẹ ara wa wò, kí á tún ọ̀nà wa ṣe, kí á sì yipada sí ọ̀dọ̀ OLUWA. Ẹ jẹ́ kí á gbé ojú wa sókè, kí á ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọrun ọ̀run: “A ti ṣẹ̀, a sì ti ṣoríkunkun, ìwọ OLUWA kò sì tíì dáríjì wá. “O gbé ibinu wọ̀ bí ẹ̀wù, ò ń lépa wa, o sì ń pa wá láì ṣàánú wa. O ti fi ìkùukùu bo ara rẹ, tóbẹ́ẹ̀ tí adura kankan kò lè kọjá sọ́dọ̀ rẹ. O ti sọ wá di ààtàn ati ohun ẹ̀gbin láàrin àwọn eniyan. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ń wẹnu sí wa lára. Ẹ̀rù ati ìṣubú, ìsọdahoro ati ìparun ti dé bá wa. Omijé ń dà pòròpòrò lójú mi, nítorí ìparun àwọn eniyan mi. “Omijé yóo máa dà pòròpòrò lójú mi láì dáwọ́ dúró, ati láìsinmi. Títí OLUWA yóo fi bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, tí yóo sì rí wa.