Joṣ 24:29-33
Joṣ 24:29-33 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún. Nwọn si sin i ni àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnatisera, ti mbẹ ni ilẹ òke Efraimu, ni ìha ariwa òke Gaaṣi. Israeli si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, ti o si mọ̀ gbogbo iṣẹ OLUWA, ti o ṣe fun Israeli. Egungun Josefu, ti awọn ọmọ Israeli gbé gòke lati Egipti wá, ni nwọn si sin ni Ṣekemu, ni ipín ilẹ ti Jakobu rà lọwọ awọn ọmọ Hamori baba Ṣekemu li ọgọrun owo: o si di ilẹ-iní awọn ọmọ Josefu. Eleasari ọmọ Aaroni si kú; nwọn si sin i li òke Finehasi ọmọ rẹ̀, ti a fi fun u li òke Efraimu.
Joṣ 24:29-33 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, nígbà tó yá, Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n bá sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu, ní apá ìhà àríwá Gaaṣi. Àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua fi wà láàyè, ati ní àkókò àwọn àgbààgbà tí wọ́n ṣẹ́kù lẹ́yìn Joṣua, tí wọ́n mọ gbogbo ohun tí OLUWA ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sin egungun Josẹfu tí wọ́n gbé wá láti ilẹ̀ Ijipti sí Ṣekemu, lórí ilẹ̀ tí Jakọbu fi ọgọrun-un fadaka rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, tíí ṣe baba Ṣekemu, ilẹ̀ náà sì di àjogúnbá fún arọmọdọmọ Josẹfu. Nígbà tí ó yá, Eleasari, ọmọ Aaroni kú; wọ́n sì sin ín sí Gibea, ìlú Finehasi, ọmọ rẹ̀, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu.
Joṣ 24:29-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Joṣua ọmọ Nuni ìránṣẹ́ OLúWA, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110) Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Timnati Serah ni ilẹ̀ orí òkè Efraimu, ní ìhà àríwá Òkè Gaaṣi. Israẹli sì sin OLúWA ní gbogbo ọjọ́ ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí OLúWA ṣe fún Israẹli. Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́ọ̀rún (100) fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu. Eleasari ọmọ Aaroni sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gibeah, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Finehasi ní òkè ilẹ̀ Efraimu.