Joṣ 24

24
Joṣua Bá Àwọn Eniyan náà Sọ̀rọ̀ ní Ṣekemu
1JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun.
2Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Bayi ni OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Awọn baba nyin ti gbé ìha keji Odò nì li atijọ rí, ani Tera, baba Abrahamu, ati baba Nahori: nwọn si sìn oriṣa.
3Emi si mú Abrahamu baba nyin lati ìha keji Odò na wá, mo si ṣe amọ̀na rẹ̀ là gbogbo ilẹ Kenaani já, mo si sọ irú-ọmọ rẹ̀ di pipọ̀, mo si fun u ni Isaaki.
4Emi si fun Isaaki ni Jakobu ati Esau: mo si fun Esau li òke Seiri lati ní i; Jakobu pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ si sọkalẹ lọ si Egipti.
5Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade.
6Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa.
7Nigbati nwọn kigbepè OLUWA, o fi òkunkun si agbedemeji ẹnyin ati awọn ara Egipti, o si mú okun ya lù wọn, o si bò wọn mọlẹ; oju nyin si ti ri ohun ti mo ṣe ni Egipti: ẹnyin si gbé inu aginjù li ọjọ́ pipọ̀.
8Emi si mú nyin wá si ilẹ awọn Amori, ti ngbé ìha keji Jordani; nwọn si bá nyin jà: emi si fi wọn lé nyin lọwọ ẹnyin si ní ilẹ wọn; emi si run wọn kuro niwaju nyin.
9Nigbana ni Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu dide, o si ba Israeli jagun; o si ranṣẹ pè Balaamu ọmọ Beori lati fi nyin bú:
10Ṣugbọn emi kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; nitorina o nsure fun nyin ṣá: mo si gbà nyin kuro li ọwọ́ rẹ̀.
11Ẹnyin si gòke Jordani, ẹ si dé Jeriko: awọn ọkunrin Jeriko si fi ìja fun nyin, awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; emi si fi wọn lé nyin lọwọ.
12Emi si rán agbọ́n siwaju nyin, ti o lé wọn kuro niwaju nyin, ani awọn ọba Amori meji; ki iṣe pẹlu idà rẹ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu ọrun rẹ.
13Emi si fun nyin ni ilẹ ti iwọ kò ṣe lãla si, ati ilu ti ẹnyin kò tẹ̀dó, ẹnyin si ngbé inu wọn; ninu ọgbà-àjara ati ọgbà-igi-olifi ti ẹnyin kò gbìn li ẹnyin njẹ.
14Njẹ nitorina ẹ bẹ̀ru OLUWA, ki ẹ si ma sìn i li ododo ati li otitọ: ki ẹ si mu oriṣa wọnni kuro ti awọn baba nyin sìn ni ìha keji Odò nì, ati ni Egipti; ki ẹ si ma sìn OLUWA.
15Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sìn OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni; bi oriṣa wọnni ni ti awọn baba nyin ti o wà ni ìha keji Odò ti nsìn, tabi awọn oriṣa awọn Amori, ni ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sìn.
16Awọn enia na dahùn, nwọn si wipe, Ki a má ri ti awa o fi kọ̀ OLUWA silẹ, lati sìn oriṣa;
17Nitori OLUWA Ọlọrun wa, on li ẹniti o mú wa, ati awọn baba wa gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro li oko-ẹrú, ti o si ṣe iṣẹ-iyanu nla wọnni li oju wa, ti o si pa wa mọ́ ni gbogbo ọ̀na ti awa rìn, ati lãrin gbogbo enia ti awa là kọja:
18OLUWA si lé gbogbo awọn enia na jade kuro niwaju wa, ani awọn Amori ti ngbé ilẹ na: nitorina li awa pẹlu o ṣe ma sìn OLUWA; nitori on li Ọlọrun wa.
19Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Enyin kò le sìn OLUWA; nitoripe Ọlọrun mimọ́ li on; Ọlọrun owú li on; ki yio dari irekọja ati ẹ̀ṣẹ nyin jì nyin.
20Bi ẹnyin ba kọ̀ OLUWA silẹ, ti ẹ ba si sìn ọlọrun ajeji, nigbana ni on o pada yio si ṣe nyin ni ibi, yio si run nyin, lẹhin ti o ti ṣe nyin li ore tán.
21Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, Rárá o; ṣugbọn OLUWA li awa o sìn.
22Joṣua si wi fun awọn enia na pe, Ẹnyin li ẹlẹri si ara nyin pe, ẹnyin yàn OLUWA fun ara nyin, lati ma sìn i. Nwọn si wipe, Awa ṣe ẹlẹri.
23Njẹ nitorina ẹ mu ọlọrun ajeji ti mbẹ lãrin nyin kuro, ki ẹnyin si yi ọkàn nyin si OLUWA Ọlọrun Israeli.
24Awọn enia na si wi fun Joṣua pe, OLUWA Ọlọrun wa li awa o ma sìn, ohùn rẹ̀ li awa o si ma gbọ́.
25Bẹ̃ni Joṣua bá awọn enia na dá majẹmu li ọjọ́ na, o si fi ofin ati ìlana fun wọn ni Ṣekemu.
26Joṣua si kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwé ofin Ọlọrun, o si mú okuta nla kan, o si gbé e kà ibẹ̀ labẹ igi-oaku kan, ti o wà ni ibi-mimọ́ OLUWA.
27Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Ẹ kiyesi i, okuta yi ni ẹlẹri fun wa; nitori o ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ OLUWA ti o bá wa sọ: nitorina yio ṣe ẹlẹri si nyin, ki ẹnyin má ba sẹ́ Ọlọrun nyin.
28Bẹ̃ni Joṣua jọwọ awọn enia na lọwọ lọ, olukuluku si ilẹ-iní rẹ̀.
Joṣua ati Eleasari Kú
29O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún.
30Nwọn si sin i ni àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnatisera, ti mbẹ ni ilẹ òke Efraimu, ni ìha ariwa òke Gaaṣi.
31Israeli si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, ti o si mọ̀ gbogbo iṣẹ OLUWA, ti o ṣe fun Israeli.
32Egungun Josefu, ti awọn ọmọ Israeli gbé gòke lati Egipti wá, ni nwọn si sin ni Ṣekemu, ni ipín ilẹ ti Jakobu rà lọwọ awọn ọmọ Hamori baba Ṣekemu li ọgọrun owo: o si di ilẹ-iní awọn ọmọ Josefu.
33Eleasari ọmọ Aaroni si kú; nwọn si sin i li òke Finehasi ọmọ rẹ̀, ti a fi fun u li òke Efraimu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣ 24: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa