JOṢUA 24

24
Joṣua Bá Àwọn Eniyan náà Sọ̀rọ̀ ní Ṣekemu
1Joṣua pe gbogbo ẹ̀yà Israẹli jọ sí Ṣekemu, ó pe gbogbo àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso ilẹ̀ Israẹli; gbogbo wọn sì kó ara wọn jọ níwájú OLUWA. 2Ó wí fún gbogbo wọn pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Nígbà laelae, òkè odò Yufurate ni àwọn baba yín ń gbé: Tẹra, baba Abrahamu ati Nahori. Oriṣa ni wọ́n ń bọ nígbà náà.#Jẹn 11:27 3Láti òdìkejì odò náà ni mo ti mú Abrahamu baba yín, mo sìn ín la gbogbo ilẹ̀ Kenaani já; mo sì sọ arọmọdọmọ rẹ̀ di pupọ. Mo fún un ní Isaaki;#a Jẹn 12:1-9; b Jẹn 21:1-3 4mo sì fún Isaaki ni Jakọbu ati Esau. Mo fún Esau ní òkè Seiri bí ohun ìní tirẹ̀, ṣugbọn Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti.#a Jẹn 25:24-26; b Jẹn 36:8; Diut 2:5; d Jẹn 46:1-7 5Mo rán Mose ati Aaroni sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ará Ijipti jà, lẹ́yìn náà mo ko yín jáde.#Eks 3:1–12:42 6Mo kó àwọn baba yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ẹ dé etí òkun, àwọn ará Ijipti kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì lé àwọn baba yín títí dé etí Òkun Pupa. 7Nígbà tí àwọn baba yín ké pe OLUWA, OLUWA fi òkùnkùn sí ààrin ẹ̀yin ati àwọn ará Ijipti, ó sì mú kí òkun bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin náà ṣá fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ijipti.#Eks 14:1-31.
“ ‘Ẹ wà ninu aṣálẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, 8lẹ́yìn náà mo ko yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani. Wọ́n ba yín jà, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ẹ gba ilẹ̀ wọn, mo sì pa wọ́n run lójú yín.#Nọm 21:21-35 9Lẹ́yìn náà, Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu, dìde láti bá Israẹli jagun, ó ranṣẹ sí Balaamu, ọmọ Beori, láti wá fi yín gégùn-ún. 10Ṣugbọn n kò fetísí ọ̀rọ̀ Balaamu; nítorí náà ìre ni ó sú fun yín, mo sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ rẹ̀.#Nọm 22:1–24:25 11Ẹ gun òkè odò Jọdani wá sí Jẹriko, àwọn ará Jẹriko sì gbógun tì yín, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.#a Joṣ 3:14-17; b Joṣ 6:1-21 12Kì í ṣe idà tabi ọfà ni ẹ fi ṣẹgun àwọn ọba ará Amori mejeeji, agbọ́n ni mo rán ṣáájú yín tí ó sì lé wọn jáde fun yín.#Eks 23:28; Diut 7:20 13Mo fun yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò ṣe làálàá fún, ati àwọn ìlú ńláńlá, tí ẹ kò tẹ̀ dó, ẹ sì ń gbé ibẹ̀. Ẹ̀ ń jẹ èso àjàrà ati ti igi olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn.’#Diut 6:10-11
14“Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú. Ẹ kó gbogbo oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò ati ní Ijipti dànù, kí ẹ sì máa sin OLUWA. 15Bí kò bá wá wù yín láti máa sin OLUWA, ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí. Kì báà ṣe àwọn oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò, tabi oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn ní tèmi ati ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.”
16Nígbà náà ni àwọn eniyan náà dáhùn, wọ́n ní, “Kí á má rí i pé a kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń bọ oriṣa. 17Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun wa ni ó kó àwa ati àwọn baba wa jáde ní oko ẹrú ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀n-ọn-nì lójú wa. Òun ni ó dá ẹ̀mí wa sí ní gbogbo ọ̀nà tí a tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a là kọjá. 18OLUWA sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà kúrò níwájú wa ati àwọn ará Amori tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀. Nítorí náà OLUWA ni a óo máa sìn nítorí pé òun ni Ọlọrun wa.”
19Ṣugbọn Joṣua dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ kò lè sin OLUWA, nítorí pé Ọlọrun mímọ́ ni, Ọlọrun owú sì ni pẹlu, kò sì ní dárí àwọn àìṣedéédé ati ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín. 20Lẹ́yìn tí OLUWA bá ti ṣe yín lóore, bí ẹ bá kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí ẹ sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ àwọn oriṣa àjèjì, yóo yipada láti ṣe yín níbi, yóo sì pa yín run.”
21Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “Rárá o, OLUWA ni a óo máa sìn.”
22Joṣua bá wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí ara yín, pé OLUWA ni ẹ yàn láti máa sìn.”
Wọ́n dáhùn pé, “Àwa ni ẹlẹ́rìí.”
23Lẹ́yìn náà, Joṣua sọ fún wọn pé, “Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ kó àwọn oriṣa àjèjì tí ó wà láàrin yín dànù, kí ẹ sì fi ọkàn sọ́dọ̀ OLUWA Ọlọrun Israẹli.”
24Àwọn eniyan náà dá Joṣua lóhùn pé, “OLUWA Ọlọrun wa ni a óo máa sìn, tirẹ̀ ni a óo sì máa gbọ́.”
25Joṣua bá dá majẹmu pẹlu àwọn eniyan náà ní ọjọ́ náà, ó sì ṣe òfin ati ìlànà fún wọn ní Ṣekemu. 26Ó kọ ọ̀rọ̀ náà sinu ìwé òfin Ọlọrun, ó gbé òkúta ńlá kan, ó sì fi gúnlẹ̀ lábẹ́ igi Oaku, ní ibi mímọ́ OLUWA, 27ó bá wí fún gbogbo wọn pé, “Ẹ wo òkúta yìí, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin wa, nítorí pé ó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ fún wa, nítorí náà, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín, kí ẹ má baà hùwà aiṣododo sí Ọlọrun yín.” 28Joṣua bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà máa lọ, kí olukuluku pada sí orí ilẹ̀ rẹ̀.
Joṣua ati Eleasari Kú
29Lẹ́yìn náà, nígbà tó yá, Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. 30Wọ́n bá sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu, ní apá ìhà àríwá Gaaṣi.#Joṣ 19:49-50.
31Àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua fi wà láàyè, ati ní àkókò àwọn àgbààgbà tí wọ́n ṣẹ́kù lẹ́yìn Joṣua, tí wọ́n mọ gbogbo ohun tí OLUWA ṣe fún Israẹli.
32Àwọn ọmọ Israẹli sin egungun Josẹfu tí wọ́n gbé wá láti ilẹ̀ Ijipti sí Ṣekemu, lórí ilẹ̀ tí Jakọbu fi ọgọrun-un fadaka rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, tíí ṣe baba Ṣekemu, ilẹ̀ náà sì di àjogúnbá fún arọmọdọmọ Josẹfu.#Jẹn 33:19; 50:24-25; Eks 13:19; Joh 4:5; A. Apo 7:16.
33Nígbà tí ó yá, Eleasari, ọmọ Aaroni kú; wọ́n sì sin ín sí Gibea, ìlú Finehasi, ọmọ rẹ̀, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

JOṢUA 24: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀