Joṣ 24:25-33

Joṣ 24:25-33 Yoruba Bible (YCE)

Joṣua bá dá majẹmu pẹlu àwọn eniyan náà ní ọjọ́ náà, ó sì ṣe òfin ati ìlànà fún wọn ní Ṣekemu. Ó kọ ọ̀rọ̀ náà sinu ìwé òfin Ọlọrun, ó gbé òkúta ńlá kan, ó sì fi gúnlẹ̀ lábẹ́ igi Oaku, ní ibi mímọ́ OLUWA, ó bá wí fún gbogbo wọn pé, “Ẹ wo òkúta yìí, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí láàrin wa, nítorí pé ó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLUWA ti sọ fún wa, nítorí náà, òun ni yóo jẹ́ ẹlẹ́rìí fun yín, kí ẹ má baà hùwà aiṣododo sí Ọlọrun yín.” Joṣua bá pàṣẹ pé kí àwọn eniyan náà máa lọ, kí olukuluku pada sí orí ilẹ̀ rẹ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tó yá, Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú nígbà tí ó di ẹni aadọfa (110) ọdún. Wọ́n bá sin ín sórí ilẹ̀ rẹ̀ ní Timnati Sera, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu, ní apá ìhà àríwá Gaaṣi. Àwọn ọmọ Israẹli sin OLUWA ní gbogbo àkókò tí Joṣua fi wà láàyè, ati ní àkókò àwọn àgbààgbà tí wọ́n ṣẹ́kù lẹ́yìn Joṣua, tí wọ́n mọ gbogbo ohun tí OLUWA ṣe fún Israẹli. Àwọn ọmọ Israẹli sin egungun Josẹfu tí wọ́n gbé wá láti ilẹ̀ Ijipti sí Ṣekemu, lórí ilẹ̀ tí Jakọbu fi ọgọrun-un fadaka rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hamori, tíí ṣe baba Ṣekemu, ilẹ̀ náà sì di àjogúnbá fún arọmọdọmọ Josẹfu. Nígbà tí ó yá, Eleasari, ọmọ Aaroni kú; wọ́n sì sin ín sí Gibea, ìlú Finehasi, ọmọ rẹ̀, tí ó wà ní agbègbè olókè Efuraimu.

Joṣ 24:25-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọjọ́ náà Joṣua dá májẹ̀mú fún àwọn ènìyàn, ó sì fi òfin àti ìlànà fún wọn ní Ṣekemu. Joṣua sì kọ gbogbo ìdáhùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí sí inú Ìwé Òfin Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà ó gbé òkúta ńlá kan, ó gbé e kalẹ̀ ní abẹ́ igi óákù ní ẹ̀bá ibi mímọ́ OLúWA. “E wò ó!” ó wí fún gbogbo ènìyàn pé, “Òkúta yìí ni yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí fún wa, nítorí ó ti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tí OLúWA ti sọ fún wa. Yóò jẹ́ ẹlẹ́rìí yín tí ẹ bá ṣe àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run yín.” Lẹ́yìn náà ni Joṣua jẹ́ kí àwọn ènìyàn lọ, olúkúlùkù sí ilẹ̀ ìní rẹ̀. Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Joṣua ọmọ Nuni ìránṣẹ́ OLúWA, kú ní ẹni àádọ́fà ọdún (110) Wọ́n sì sin ín sí ilẹ̀ ìní rẹ̀, ní Timnati Serah ni ilẹ̀ orí òkè Efraimu, ní ìhà àríwá Òkè Gaaṣi. Israẹli sì sin OLúWA ní gbogbo ọjọ́ ayé Joṣua àti ní gbogbo ọjọ́ àwọn àgbàgbà tí ó wà lẹ́yìn ikú rẹ̀ tí wọ́n sì rí gbogbo iṣẹ́ ńlá tí OLúWA ṣe fún Israẹli. Egungun Josẹfu, èyí tí àwọn ọmọ Israẹli kó kúrò ní Ejibiti, ni wọ́n sin ní Ṣekemu ní ìpín ilẹ̀ tí Jakọbu rà fún ọgọ́ọ̀rún (100) fàdákà ní ọwọ́ Hamori, baba Ṣekemu. Èyí sì jẹ́ ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Josẹfu. Eleasari ọmọ Aaroni sì kú, wọ́n sì sin ín ní Gibeah, tí a ti pín fún ọmọ rẹ̀ Finehasi ní òkè ilẹ̀ Efraimu.