Joṣ 24:1-18

Joṣ 24:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

JOṢUA si pè gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli jọ si Ṣekemu, o si pè awọn àgba Israeli, ati awọn olori wọn, ati awọn onidajọ wọn, ati awọn ijoye wọn; nwọn si fara wọn hàn niwaju Ọlọrun. Joṣua si wi fun gbogbo awọn enia pe, Bayi ni OLUWA, Ọlọrun Israeli wi, Awọn baba nyin ti gbé ìha keji Odò nì li atijọ rí, ani Tera, baba Abrahamu, ati baba Nahori: nwọn si sìn oriṣa. Emi si mú Abrahamu baba nyin lati ìha keji Odò na wá, mo si ṣe amọ̀na rẹ̀ là gbogbo ilẹ Kenaani já, mo si sọ irú-ọmọ rẹ̀ di pipọ̀, mo si fun u ni Isaaki. Emi si fun Isaaki ni Jakobu ati Esau: mo si fun Esau li òke Seiri lati ní i; Jakobu pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ si sọkalẹ lọ si Egipti. Mo si rán Mose ati Aaroni, mo si yọ Egipti lẹnu, gẹgẹ bi eyiti mo ṣe lãrin rẹ̀: lẹhin na mo si mú nyin jade. Emi si mú awọn baba nyin jade kuro ni Egipti: ẹnyin si dé okun; awọn ara Egipti si lepa awọn baba nyin ti awọn ti kẹkẹ́ ati ẹlẹṣin dé Okun Pupa. Nigbati nwọn kigbepè OLUWA, o fi òkunkun si agbedemeji ẹnyin ati awọn ara Egipti, o si mú okun ya lù wọn, o si bò wọn mọlẹ; oju nyin si ti ri ohun ti mo ṣe ni Egipti: ẹnyin si gbé inu aginjù li ọjọ́ pipọ̀. Emi si mú nyin wá si ilẹ awọn Amori, ti ngbé ìha keji Jordani; nwọn si bá nyin jà: emi si fi wọn lé nyin lọwọ ẹnyin si ní ilẹ wọn; emi si run wọn kuro niwaju nyin. Nigbana ni Balaki ọmọ Sipporu, ọba Moabu dide, o si ba Israeli jagun; o si ranṣẹ pè Balaamu ọmọ Beori lati fi nyin bú: Ṣugbọn emi kò fẹ́ fetisi ti Balaamu; nitorina o nsure fun nyin ṣá: mo si gbà nyin kuro li ọwọ́ rẹ̀. Ẹnyin si gòke Jordani, ẹ si dé Jeriko: awọn ọkunrin Jeriko si fi ìja fun nyin, awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, awọn Hifi, ati awọn Jebusi; emi si fi wọn lé nyin lọwọ. Emi si rán agbọ́n siwaju nyin, ti o lé wọn kuro niwaju nyin, ani awọn ọba Amori meji; ki iṣe pẹlu idà rẹ, bẹ̃ni ki iṣe pẹlu ọrun rẹ. Emi si fun nyin ni ilẹ ti iwọ kò ṣe lãla si, ati ilu ti ẹnyin kò tẹ̀dó, ẹnyin si ngbé inu wọn; ninu ọgbà-àjara ati ọgbà-igi-olifi ti ẹnyin kò gbìn li ẹnyin njẹ. Njẹ nitorina ẹ bẹ̀ru OLUWA, ki ẹ si ma sìn i li ododo ati li otitọ: ki ẹ si mu oriṣa wọnni kuro ti awọn baba nyin sìn ni ìha keji Odò nì, ati ni Egipti; ki ẹ si ma sìn OLUWA. Bi o ba si ṣe buburu li oju nyin lati sìn OLUWA, ẹ yàn ẹniti ẹnyin o ma sìn li oni; bi oriṣa wọnni ni ti awọn baba nyin ti o wà ni ìha keji Odò ti nsìn, tabi awọn oriṣa awọn Amori, ni ilẹ ẹniti ẹnyin ngbé: ṣugbọn bi o ṣe ti emi ati ile mi ni, OLUWA li awa o ma sìn. Awọn enia na dahùn, nwọn si wipe, Ki a má ri ti awa o fi kọ̀ OLUWA silẹ, lati sìn oriṣa; Nitori OLUWA Ọlọrun wa, on li ẹniti o mú wa, ati awọn baba wa gòke lati ilẹ Egipti wá, kuro li oko-ẹrú, ti o si ṣe iṣẹ-iyanu nla wọnni li oju wa, ti o si pa wa mọ́ ni gbogbo ọ̀na ti awa rìn, ati lãrin gbogbo enia ti awa là kọja: OLUWA si lé gbogbo awọn enia na jade kuro niwaju wa, ani awọn Amori ti ngbé ilẹ na: nitorina li awa pẹlu o ṣe ma sìn OLUWA; nitori on li Ọlọrun wa.

Joṣ 24:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Joṣua pe gbogbo ẹ̀yà Israẹli jọ sí Ṣekemu, ó pe gbogbo àwọn àgbààgbà, àwọn olórí, àwọn onídàájọ́, ati àwọn alákòóso ilẹ̀ Israẹli; gbogbo wọn sì kó ara wọn jọ níwájú OLUWA. Ó wí fún gbogbo wọn pé, “Báyìí ni OLUWA Ọlọrun Israẹli wí, ‘Nígbà laelae, òkè odò Yufurate ni àwọn baba yín ń gbé: Tẹra, baba Abrahamu ati Nahori. Oriṣa ni wọ́n ń bọ nígbà náà. Láti òdìkejì odò náà ni mo ti mú Abrahamu baba yín, mo sìn ín la gbogbo ilẹ̀ Kenaani já; mo sì sọ arọmọdọmọ rẹ̀ di pupọ. Mo fún un ní Isaaki; mo sì fún Isaaki ni Jakọbu ati Esau. Mo fún Esau ní òkè Seiri bí ohun ìní tirẹ̀, ṣugbọn Jakọbu ati àwọn ọmọ rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ijipti. Mo rán Mose ati Aaroni sí wọn ní ilẹ̀ Ijipti, mo fi àjàkálẹ̀ àrùn bá àwọn ará Ijipti jà, lẹ́yìn náà mo ko yín jáde. Mo kó àwọn baba yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti. Nígbà tí ẹ dé etí òkun, àwọn ará Ijipti kó kẹ̀kẹ́ ogun ati àwọn ẹlẹ́ṣin, wọ́n sì lé àwọn baba yín títí dé etí Òkun Pupa. Nígbà tí àwọn baba yín ké pe OLUWA, OLUWA fi òkùnkùn sí ààrin ẹ̀yin ati àwọn ará Ijipti, ó sì mú kí òkun bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ̀yin náà ṣá fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ijipti. “ ‘Ẹ wà ninu aṣálẹ̀ fún ìgbà pípẹ́, lẹ́yìn náà mo ko yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí wọn ń gbé òdìkejì odò Jọdani. Wọ́n ba yín jà, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Ẹ gba ilẹ̀ wọn, mo sì pa wọ́n run lójú yín. Lẹ́yìn náà, Balaki, ọmọ Sipori, ọba Moabu, dìde láti bá Israẹli jagun, ó ranṣẹ sí Balaamu, ọmọ Beori, láti wá fi yín gégùn-ún. Ṣugbọn n kò fetísí ọ̀rọ̀ Balaamu; nítorí náà ìre ni ó sú fun yín, mo sì gbà yín kúrò lọ́wọ́ rẹ̀. Ẹ gun òkè odò Jọdani wá sí Jẹriko, àwọn ará Jẹriko sì gbógun tì yín, ati àwọn ará Amori, àwọn ará Perisi, àwọn ará Kenaani, àwọn ará Hiti, àwọn ará Girigaṣi, àwọn ará Hifi, ati àwọn ará Jebusi, mo sì fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Kì í ṣe idà tabi ọfà ni ẹ fi ṣẹgun àwọn ọba ará Amori mejeeji, agbọ́n ni mo rán ṣáájú yín tí ó sì lé wọn jáde fun yín. Mo fun yín ní ilẹ̀ tí ẹ kò ṣe làálàá fún, ati àwọn ìlú ńláńlá, tí ẹ kò tẹ̀ dó, ẹ sì ń gbé ibẹ̀. Ẹ̀ ń jẹ èso àjàrà ati ti igi olifi tí kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ gbìn.’ “Nítorí náà, ẹ bẹ̀rù OLUWA, kí ẹ sì máa sìn ín tọkàntọkàn pẹlu òtítọ́ inú. Ẹ kó gbogbo oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò ati ní Ijipti dànù, kí ẹ sì máa sin OLUWA. Bí kò bá wá wù yín láti máa sin OLUWA, ẹ yan ẹni tí ó bá wù yín láti máa sìn lónìí. Kì báà ṣe àwọn oriṣa tí àwọn baba yín ń bọ ní òdìkejì odò, tabi oriṣa àwọn ará Amori tí ẹ̀ ń gbé ilẹ̀ wọn. Ṣugbọn ní tèmi ati ilé mi, OLUWA ni àwa óo máa sìn.” Nígbà náà ni àwọn eniyan náà dáhùn, wọ́n ní, “Kí á má rí i pé a kọ OLUWA sílẹ̀, a sì ń bọ oriṣa. Nítorí pé, OLUWA Ọlọrun wa ni ó kó àwa ati àwọn baba wa jáde ní oko ẹrú ilẹ̀ Ijipti, òun ni ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀n-ọn-nì lójú wa. Òun ni ó dá ẹ̀mí wa sí ní gbogbo ọ̀nà tí a tọ̀ láàrin gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè tí a là kọjá. OLUWA sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè náà kúrò níwájú wa ati àwọn ará Amori tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà tẹ́lẹ̀. Nítorí náà OLUWA ni a óo máa sìn nítorí pé òun ni Ọlọrun wa.”

Joṣ 24:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà náà ni Joṣua pe gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli jọ ní Ṣekemu. Ó pe àwọn àgbàgbà, àwọn olórí, onídàájọ́ àti àwọn ìjòyè Israẹli, wọ́n sì fi ara wọn hàn níwájú Ọlọ́run. Joṣua sì sọ fun gbogbo ènìyàn pé, “Báyìí ni OLúWA Ọlọ́run Israẹli, wí: ‘Nígbà kan rí àwọn baba ńlá yín Tẹra baba Abrahamu àti Nahori ń gbé ní ìkọjá odò Eufurate, wọ́n sì sin àwọn òrìṣà. Ṣùgbọ́n mo mú Abrahamu baba yín kúrò ní ìkọjá odò Eufurate, mo sì ṣe amọ̀nà rẹ̀ ni gbogbo Kenaani, mo sì fún ní àwọn ọmọ púpọ̀. Mo fún ní Isaaki, àti fún Isaaki ni mo fún ní Jakọbu àti Esau, mo sì fún Esau ní ilẹ̀ orí òkè Seiri ní ìní, ṣùgbọ́n Jakọbu àti àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti. “ ‘Nígbà náà ni mo rán Mose àti Aaroni, mo sì yọ Ejibiti lẹ́nu ní ti nǹkan tí mo ṣe níbẹ̀, mo sì mú yín jáde. Nígbà tí mo mú àwọn baba yín jáde kúrò ní Ejibiti, ẹ wá sí Òkun, àwọn ará Ejibiti lépa wọn pẹ̀lú kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́ṣin títí ó fi dé Òkun Pupa. Ṣùgbọ́n wọ́n ké pe OLúWA fún ìrànlọ́wọ́, ó sì fi òkùnkùn sí àárín yín àti àwọn ará Ejibiti, ó sì mú Òkun wá sí orí wọn; ó sì bò wọ́n mọ́lẹ̀. Ẹ sì fi ojú yín rí ohun tí mo ṣe sí àwọn ará Ejibiti. Lẹ́yìn náà ẹ sì gbé ní aginjù fún ọjọ́ pípẹ́. “ ‘Èmi mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn ará Amori tí ó ń gbé ìlà-oòrùn Jordani. Wọ́n bá yín jà, Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́. Èmí pa wọ́n run kúrò níwájú u yín, ẹ sì gba ilẹ̀ ẹ wọn. Nígbà tí Balaki ọmọ Sippori, ọba Moabu, múra láti bá Israẹli jà, ó ránṣẹ́ sí Balaamu ọmọ Beori láti fi yín bú. Ṣùgbọ́n èmi kò fetí sí Balaamu, bẹ́ẹ̀ ni ó súre fún un yín síwájú àti síwájú sí i, mo sì gbà yín kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. “ ‘Lẹ́yìn náà ni ẹ rékọjá Jordani, tí ẹ sì wá sí Jeriko. Àwọn ará ìlú Jeriko sì bá yín jà, gẹ́gẹ́ bí ará Amori, Peresi, Kenaani, Hiti, Girgaṣi, Hifi àti Jebusi. Ṣùgbọ́n mo fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́. Èmi sì rán oyin sí iwájú yín, tí ó lé wọn kúrò ní iwájú yín, àní ọba Amori méjì. Ẹ kò ṣe èyí pẹ̀lú idà yín àti ọrun yín. Bẹ́ẹ̀ ni mo fún un yín ní ilẹ̀ tí ẹ̀yin kò ṣiṣẹ́ fún, àti àwọn ìlú tí ẹ̀ yin kò kọ́; ẹ sì ń gbé inú wọn, ẹ sì ń jẹ nínú ọgbà àjàrà àti ọgbà olifi tí ẹ kò gbìn.’ “Nísinsin yìí ẹ bẹ̀rù OLúWA, kí ẹ sì máa sìn ín ní òtítọ́ àti òdodo. Kí ẹ sì mú òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate àti ní Ejibiti kúrò, kí ẹ sì máa sin OLúWA. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá fẹ́ láti sin OLúWA, nígbà náà ẹ yàn fún ara yín ní òní ẹni tí ẹ̀yin yóò sìn bóyá òrìṣà tí àwọn baba ńlá yín sìn ní ìkọjá odò Eufurate, tàbí òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ní ti èmi àti ilé mi, OLúWA ni àwa yóò máa sìn.” Àwọn ènìyàn sì dáhùn pé, “Kí a má ri tí àwa yóò fi kọ OLúWA sílẹ̀ láti sin òrìṣà! Nítorí OLúWA Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni ó gba àwọn baba ńlá wa là kúrò ní Ejibiti, ní oko ẹrú. Òun ni Ọlọ́run tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ńlá níwájú àwọn ọmọ Israẹli. Ó pa wá mọ́ nínú gbogbo ìrìnàjò wa àti ní àárín gbogbo orílẹ̀-èdè tí a là kọjá. OLúWA sì lé gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè jáde kúrò ní iwájú wa, pẹ̀lú àwọn Amori, tí ń gbé ilẹ̀ náà. Àwa náà yóò máa sin OLúWA, nítorí òun ni Ọlọ́run wa.”