Joṣ 20:1-9
Joṣ 20:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
OLUWA si sọ fun Joṣua pe, Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ yàn ilu àbo fun ara nyin, ti mo ti sọ fun nyin lati ọwọ́ Mose wa: Ki apania ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan li aimọ̀ ki o le salọ sibẹ̀: nwọn o si jẹ́ àbo fun nyin lọwọ olugbẹsan ẹ̀jẹ. On o si salọ si ọkan ninu ilu wọnni, yio si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na, yio si rò ẹjọ́ rẹ̀ li etí awọn àgba ilu na, nwọn o si gbà a sọdọ sinu ilu na, nwọn o si fun u ni ibi kan, ki o le ma bá wọn gbé. Bi olugbẹsan ẹ̀jẹ ba lepa rẹ̀, njẹ ki nwọn ki o má ṣe fi apania na lé e lọwọ; nitoriti o pa aladugbo rẹ̀ li aimọ̀, ti kò si korira rẹ̀ tẹlẹrí. On o si ma gbé inu ilu na, titi yio fi duro niwaju ijọ fun idajọ, titi ikú olori alufa o wà li ọjọ́ wọnni: nigbana ni apania na yio pada, on o si wá si ilu rẹ̀, ati si ile rẹ̀, si ilu na lati ibiti o gbé ti salọ. Nwọn si yàn Kedeṣi ni Galili ni ilẹ òke Naftali, ati Ṣekemu ni ilẹ òke Efraimu, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni) ni ilẹ òke Juda. Ati ni ìha keji Jordani lẹba Jeriko ni ìla-õrùn, nwọn yàn Beseri li aginjù ni pẹtẹlẹ̀ ninu ẹ̀ya Reubeni, ati Ramotu ni Gileadi ninu ẹ̀ya Gadi, ati Golani ni Baṣani ninu ẹ̀ya Manasse. Wọnyi ni awọn ilu ti a yàn fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo lãrin wọn, ki ẹnikẹni ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan, ki o le salọ sibẹ̀, ki o má ba si ti ọwọ́ olugbẹsan ẹ̀jẹ ku, titi on o fi duro niwaju ijọ.
Joṣ 20:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà, OLUWA sọ fún Joṣua pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n yan àwọn ìlú ààbò tí mo bá Mose sọ nípa rẹ̀, pé kí ó sọ fun yín. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sibẹ. Ibẹ̀ ni yóo jẹ́ ibi ààbò fun yín tí ọwọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ kò fi ní máa tẹ̀ yín. Kí ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan sá lọ sí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọ̀hún, kí ó dúró ní ẹnubodè ìlú, kí ó sì ro ẹjọ́ fún àwọn àgbààgbà ibẹ̀. Wọn yóo mú un wọ inú ìlú lọ, wọn yóo fún un ní ibi tí yóo máa gbé, yóo sì wà ní ọ̀dọ̀ wọn. Bí ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ bá ń lé e bọ̀, wọn kò ní fi lé e lọ́wọ́, nítorí pé ó ṣèèṣì pa aládùúgbò rẹ̀ ni, kò sì ní ìkùnsínú sí i tẹ́lẹ̀. Ìlú yìí ni yóo máa gbé títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀, yóo máa gbé ibẹ̀ títí tí ẹni tí ó jẹ́ olórí alufaa ní àkókò náà yóo fi kú, lẹ́yìn náà ẹni tí ó ṣèèṣì pa eniyan yìí lè pada lọ sí ilé rẹ̀ ati sí ìlú rẹ̀ níbi tí ó ti sá wá.” Wọ́n ya Kedeṣi sọ́tọ̀ ní Galili ní agbègbè olókè ti Nafutali, ati Ṣekemu ní agbègbè olókè ti Efuraimu, ati Kiriati Ariba (tí wọ́n ń pè ní Heburoni), ní agbègbè olókè ti Juda. Ní òdìkejì odò Jọdani, ní apá ìlà oòrùn Jẹriko, wọ́n ya Beseri tí ó wà ninu aṣálẹ̀ ní ilẹ̀ tí ó tẹ́jú sọ́tọ̀. Wọ́n ya Ramoti tí ó wà ní Gileadi sọ́tọ̀ ní agbègbè ti ẹ̀yà Gadi, ati Golani tí ó wà ní Baṣani, ní agbègbè ti ẹ̀yà Manase. Àwọn ìlú ọ̀hún ni ìlú ààbò tí wọ́n yàn fún àwọn ọmọ Israẹli, ati fún àwọn àlejò tí wọ́n ń gbé ààrin wọn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣèèṣì pa eniyan lè sá lọ sí èyíkéyìí ninu wọn, yóo sì bọ́ lọ́wọ́ ẹni tí ń gbẹ̀san ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títí tí àwọn ìgbìmọ̀ yóo fi ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
Joṣ 20:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà náà ni OLúWA sọ fún Joṣua pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọn yan àwọn ìlú ààbò, gẹ́gẹ́ bí mo ti pàṣẹ fún ọ láti ẹnu Mose, kí ẹni tí ó bá ṣèèṣì pa ènìyàn tàbí tí ó bá pa ènìyàn láìmọ̀-ọ́n-mọ̀ lè sálọ sí ibẹ̀, fún ààbò lọ́wọ́ olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ẹni tí ó pa. Nígbà tí ó bá sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, yóò sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà àtiwọ ibodè ìlú, kí ó sì ṣe àlàyé ara rẹ̀ ní iwájú àwọn àgbàgbà ìlú náà. Nígbà náà ni wọn yóò gbà á sí ìlú wọn, wọn yóò sì fun ní ibùgbé láàrín wọn. Bí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ bá ń lépa rẹ̀, wọn kò gbọdọ̀ fi àwọn ọ̀daràn náà lé wọn lọ́wọ́, nítorí tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ láìmọ̀, tí kò sì kórìíra rẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí. Òun ó sì máa gbé inú ìlú náà, títí yóò fi jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn àti títí ikú olórí àlùfáà tí ó ń ṣiṣẹ́ ìsìn nígbà náà. Nígbà náà ó lè padà sí ilé rẹ̀ ní ìlú tí ó ti sá wá.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n yan Kedeṣi ní Galili ní ìlú òkè Naftali, Ṣekemu ní ìlú òkè Efraimu, àti Kiriati-Arba (tí í ṣe, Hebroni) ní ìlú òkè Juda. Ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani ti Jeriko, wọ́n ya Beseri ní aginjù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ẹ̀yà Reubeni, Ramoti ní Gileadi ní ẹ̀yà Gadi, àti Golani ní Baṣani ní ẹ̀yà Manase. Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Israẹli tàbí àlejò tí ń gbé ní àárín wọn tí ó ṣèèṣì pa ẹnìkan lè sálọ sí àwọn ìlú tí a yà sọ́tọ̀ wọ̀nyí, kí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ má sì ṣe pa á kí ó to di àkókò tí yóò jẹ́jọ́ níwájú ìjọ ènìyàn.