Joṣ 20

20
Àwọn Ìlú Ààbò
1OLUWA si sọ fun Joṣua pe,
2Wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹ yàn ilu àbo fun ara nyin, ti mo ti sọ fun nyin lati ọwọ́ Mose wa:
3Ki apania ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan li aimọ̀ ki o le salọ sibẹ̀: nwọn o si jẹ́ àbo fun nyin lọwọ olugbẹsan ẹ̀jẹ.
4On o si salọ si ọkan ninu ilu wọnni, yio si duro li ẹnu-ọ̀na ibode ilu na, yio si rò ẹjọ́ rẹ̀ li etí awọn àgba ilu na, nwọn o si gbà a sọdọ sinu ilu na, nwọn o si fun u ni ibi kan, ki o le ma bá wọn gbé.
5Bi olugbẹsan ẹ̀jẹ ba lepa rẹ̀, njẹ ki nwọn ki o má ṣe fi apania na lé e lọwọ; nitoriti o pa aladugbo rẹ̀ li aimọ̀, ti kò si korira rẹ̀ tẹlẹrí.
6On o si ma gbé inu ilu na, titi yio fi duro niwaju ijọ fun idajọ, titi ikú olori alufa o wà li ọjọ́ wọnni: nigbana ni apania na yio pada, on o si wá si ilu rẹ̀, ati si ile rẹ̀, si ilu na lati ibiti o gbé ti salọ.
7Nwọn si yàn Kedeṣi ni Galili ni ilẹ òke Naftali, ati Ṣekemu ni ilẹ òke Efraimu, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni) ni ilẹ òke Juda.
8Ati ni ìha keji Jordani lẹba Jeriko ni ìla-õrùn, nwọn yàn Beseri li aginjù ni pẹtẹlẹ̀ ninu ẹ̀ya Reubeni, ati Ramotu ni Gileadi ninu ẹ̀ya Gadi, ati Golani ni Baṣani ninu ẹ̀ya Manasse.
9Wọnyi ni awọn ilu ti a yàn fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ati fun alejò ti nṣe atipo lãrin wọn, ki ẹnikẹni ti o ba ṣeṣì pa ẹnikan, ki o le salọ sibẹ̀, ki o má ba si ti ọwọ́ olugbẹsan ẹ̀jẹ ku, titi on o fi duro niwaju ijọ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Joṣ 20: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa