Jon 2:7-10
Jon 2:7-10 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati o rẹ ọkàn mi ninu mi, emi ranti Oluwa: adura mi si wá sọdọ rẹ sinu tempili mimọ́ rẹ. Awọn ti nkiyesi eke asan kọ̀ ãnu ara wọn silẹ. Ṣugbọn emi o fi ohùn idupẹ rubọ si ọ; emi o san ẹjẹ́ ti mo ti jẹ. Ti Oluwa ni igbala. Oluwa si sọ fun ẹja na, o si pọ̀ Jona sori ilẹ gbigbẹ.
Jon 2:7-10 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ẹ̀mí mi ń bọ́ lọ, mo gbadura sí ìwọ OLUWA, o sì gbọ́ adura mi ninu tẹmpili mímọ́ rẹ. Àwọn tí wọn ń sin àwọn oriṣa lásánlàsàn kọ̀, wọn kò pa ìlérí wọn sí ọ mọ́. Ṣugbọn n óo rúbọ sí ọ pẹlu ohùn ọpẹ́, n óo sì san ẹ̀jẹ́ mi. Ti OLUWA ni ìgbàlà!” OLUWA bá pàṣẹ fún ẹja tí ó gbé Jona mì, ó sì lọ pọ̀ ọ́ sí èbúté, lórí ilẹ̀ gbígbẹ.
Jon 2:7-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, OLúWA, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ. “Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA.’ ” OLúWA sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jona sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.