Jon 2

2
Adura Jona
1NIGBANA ni Jona gbadura si Oluwa Ọlọrun rẹ̀ lati inu ẹja na wá,
2O si wipe, Emi kigbe nitori ipọnju mi si Oluwa, on si gbohùn mi; mo kigbe lati inu ipo-okú, iwọ si ti gbohùn mi.
3Nitoriti iwọ ti sọ mi sinu ibu, larin okun; iṣàn omi si yi mi kakiri; gbogbo bibì omi ati riru omi rẹ kọja lori mi.
4Nigbana ni mo wipe, A ta mi nù kuro niwaju rẹ; ṣugbọn sibẹ emi o tun ma wo iha tempili mimọ́ rẹ.
5Omi yi mi kakiri, ani titi de ọkàn; ibu yi mi kakiri, a fi koriko-odò wé mi lori.
6Emi sọkalẹ lọ si isalẹ awọn oke nla; ilẹ aiye pẹlu idenà rẹ̀ wà yi mi ka titi: ṣugbọn iwọ ti mu ẹmi mi wá soke lati inu ibú wá, Oluwa Ọlọrun mi.
7Nigbati o rẹ ọkàn mi ninu mi, emi ranti Oluwa: adura mi si wá sọdọ rẹ sinu tempili mimọ́ rẹ.
8Awọn ti nkiyesi eke asan kọ̀ ãnu ara wọn silẹ.
9Ṣugbọn emi o fi ohùn idupẹ rubọ si ọ; emi o san ẹjẹ́ ti mo ti jẹ. Ti Oluwa ni igbala.
10Oluwa si sọ fun ẹja na, o si pọ̀ Jona sori ilẹ gbigbẹ.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jon 2: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀