Jona 2:7-10

Jona 2:7-10 YCB

“Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, OLúWA, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ. “Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ OLúWA.’ ” OLúWA sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ Jona sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.