Job 31:35-40
Job 31:35-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ibaṣepe ẹnikan le gbọ́ ti emi! kiyesi i, àmi mi! ki Olodumare ki o da mi lohùn! ki emi ki o si ri iwe na ti ọta mi ti kọ! Nitõtọ emi iba gbe e le ejika mi, emi iba si dì i bi ade mọ́ ori mi. Emi iba si sọ iye ìṣisẹ mi fun u, bi ọmọ-alade li emi iba sunmọ ọdọ rẹ̀. Bi ilẹ mi ba si ke fi mi sùn, tabi ti aporo rẹ̀ pẹlu si sọkun, Bi mo ba jẹ eso oko mi lainawo si i, tabi ti mo si mu ọkàn oluwa rẹ̀ fò lọ, Ki ẹgun òṣuṣu ki o hù nipo alikama, ati wèpe nipo ọka-bàba. (Ọ̀rọ Jobu pari.)
Job 31:35-40 Yoruba Bible (YCE)
Ha! Ǹ bá rí ẹni gbọ́ tèmi! (Mo ti tọwọ́ bọ̀wé, kí Olodumare dá mi lóhùn!) Ǹ bá lè ní àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn tí àwọn ọ̀tá fi kàn mí! Dájúdájú, ǹ bá gbé e lé èjìká mi, ǹ bá fi dé orí bí adé; ǹ bá sọ gbogbo ìgbésẹ̀ mi fún Ọlọrun, ǹ bá bá a sọ̀rọ̀ bí ìjòyè. “Bí ilẹ̀ mi bá kígbe ẹ̀san lé mi lórí, tí àwọn poro oko mi sì ń sọkún; tí mo bá jẹ ninu ìkórè ilẹ̀ náà láìsanwó rẹ̀, tabi tí mo sì ṣe ikú pa ẹni tí ó ni ín, kí ẹ̀gún hù lórí ilẹ̀ náà dípò ọkà, kí koríko hù dípò ọkà baali.” Ọ̀rọ̀ Jobu parí síhìn-ín.
Job 31:35-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
(“Ìbá ṣe pé ẹnìkan le gbọ́ ti èmí! Kíyèsi i, ààmì mi, kí Olódùmarè kí ó dá mi lóhùn! Kí èmí kí ó sì rí ìwé náà tí olùfisùn mi ti kọ! Nítòótọ́ èmí ìbá gbé le èjìká mi, èmi ìbá sì dé bí adé mọ́ orí mi. Èmi ìbá sì sọ iye ìṣísẹ̀ mi fún un, bí ọmọ-aládé ni èmi ìbá súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.) “Bí ilẹ̀ mi bá sì ké rara lòdì sí mi tí a sì fi omijé kún gbogbo poro rẹ̀. Bí mo bá jẹ èso oko mi láìsan owó tàbí tí mo sì mú ọkàn olúwa rẹ̀ fò lọ, kí ẹ̀gún òṣùṣú kí ó hù dípò alikama, àti èpò búburú dípò ọkà barle.” Ọ̀rọ̀ Jobu parí.