Job 28:1-28

Job 28:1-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

NITOTỌ ipa-ilẹ fàdaka mbẹ, ati ibi ti nwọn a ma idà wura. Ninu ilẹ li a gbe nwà irin, bàba li a si ndà lati inu okuta wá. Enia li o pari òkunkun, o si ṣe awari okuta òkunkun ati ti inu ojiji ikú si iha gbogbo. Nwọn wá iho ilẹ ti o jìn si awọn ti o ngbe oke, awọn ti ẹsẹ enia gbagbe nwọn rọ si isalẹ, nwọn rọ si isalẹ jina si awọn enia. Bi o ṣe ti ilẹ ni, ninu rẹ̀ ni onjẹ ti ijade wá, ati ohun ti o wà nisalẹ li o yi soke bi ẹnipe iná. Okuta ibẹ ni ibi okuta Safiri, o si ni erupẹ wura. Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri. Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí. O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá. O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo. O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ. Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye? Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè. Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi. A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀. A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri. Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀. A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ. Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e. Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye? A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun. Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀. Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀, Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun. Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi. Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá: Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri. Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!

Job 28:1-28 Yoruba Bible (YCE)

“Dájúdájú, ibìkan wà tí wọ́n ti ń wa fadaka, ibìkan sì wà tí wọ́n ti ń yọ́ wúrà. Inú ilẹ̀ ni a ti ń wa irin, a sì ń yọ́ idẹ lára òkúta. Eniyan á sọ òkùnkùn di ìmọ́lẹ̀, a sì ṣe àwárí irin, ninu ọ̀gbun ati òkùnkùn biribiri. Wọn á gbẹ́ kòtò ninu àfonífojì, níbi tí ó jìnnà sí ibi tí eniyan ń gbé, àwọn arìnrìnàjò á gbàgbé wọn, wọn á takété sí àwọn eniyan, wọn á sì máa rọ̀ dirodiro sọ́tùn-ún sósì. Ní ti ilẹ̀, inú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde, ṣugbọn lábẹ́ rẹ̀, ó dàbí ẹnipé iná ń yí i po, ó gbóná janjan. Safire ń bẹ ninu àwọn òkúta rẹ̀, wúrà sì ni erùpẹ̀ rẹ̀. Ẹyẹ àṣá kò mọ ipa ọ̀nà ibẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ojú gúnnugún kò tó o. Àwọn ẹranko onigbeeraga kò tíì tẹ ojú ọ̀nà náà, kinniun kò sì tíì gba ibẹ̀ kọjá rí. “Eniyan á dá ọwọ́ rẹ̀ lé òkúta akọ, á gbẹ́ ẹ, á sì hú òkè ńlá tìdítìdí. Á gbẹ́ ihò sinu àpáta, ojú rẹ̀ a sì tó àwọn ìṣúra iyebíye. Á dí orísun àwọn odò, tóbẹ́ẹ̀ tí wọn kò fi lè sun, á sì wá àwọn ohun tí ó pamọ́ jáde. Ṣugbọn níbo ni a ti lè rí ọgbọ́n? Níbo sì ni ìmọ̀ wà? “Ẹnikẹ́ni kò mọ ọ̀nà ibi tí ó wà; bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ilẹ̀ alààyè. Ibú sọ pé, ‘Kò sí ninu mi,’ òkun sì ní, ‘Kò sí lọ́dọ̀ mi.’ Wúrà iyebíye kò lè rà á, fadaka kò sì ṣe é díwọ̀n iye rẹ̀. A kò lè fi wúrà Ofiri díwọ̀n iye rẹ̀, tabi òkúta onikisi tabi safire tí wọ́n jẹ́ òkúta olówó iyebíye. Ọgbọ́n níye lórí ju wúrà ati dígí lọ, a kò lè fi ohun ọ̀ṣọ́ tí a fi wúrà dáradára ṣe dípò rẹ̀. Kí á má tilẹ̀ sọ ti iyùn tabi Kristali, ọgbọ́n ní iye lórí ju òkúta Pali lọ. A kò lè fi wé òkúta topasi láti ilẹ̀ Etiopia, tabi kí á fi ojúlówó wúrà rà á. “Níbo ni ọgbọ́n ti ń wá; níbo sì ni ìmọ̀ wà? Ó pamọ́ lójú gbogbo ẹ̀dá alààyè, ati lójú àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run. Ìparun ati ikú jẹ́wọ́ pé, ‘Àhesọ ni ohun tí a gbọ́ nípa rẹ̀.’ “Ọlọrun nìkan ló mọ ọ̀nà rẹ̀, òun nìkan ló mọ ibùjókòó rẹ̀. Nítorí pé ó ń wo gbogbo ayé, ó sì ń rí ohun gbogbo tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. Nígbà tí ó fún afẹ́fẹ́ ní agbára, tí ó sì ṣe ìdíwọ̀n omi, nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì lànà fún mànàmáná. Lẹ́yìn náà ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde, ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, ó sì dán an wò. Nígbà náà ni ó sọ fún eniyan pé, ‘Wò ó, ìbẹ̀rù OLUWA ni ọgbọ́n, kí á yẹra fún ibi sì ni ìmọ̀.’ ”

Job 28:1-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà. Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá. Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí ìṣúra láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo. Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn. Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Safire, o sì ní erùpẹ̀ wúrà. Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojú gúnnugún kò rí i rí; Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí. Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá. Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo. Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe? Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè. Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”; omi Òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.” A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òṣùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀. A kò le è fi wúrà ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta Safire díye lé e. Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀. A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ. Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀. Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé? A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run. Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀. Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé. Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run, Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òṣùwọ̀n wọ́n omi. Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá, Nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde; ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí. Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”