Jobu 28:1-28

Jobu 28:1-28 YCB

Nítòótọ́, koto fàdákà ń bẹ, àti ibi tí wọ́n ti máa ń da wúrà. Nínú ilẹ̀ ni à ń gbé ń wa irin, bàbà ni a sì ń dà láti inú òkúta wá. Ènìyàn ni ó fi òpin si òkùnkùn, ó sì ṣe àwárí ìṣúra láti inú òjìji ikú sí ìhà gbogbo. Wọ́n wa ihò ilẹ̀ tí ó jì sí àwọn tí ń gbé òkè, àwọn tí ẹsẹ̀ ènìyàn gbàgbé wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀, wọ́n rọ́ sí ìsàlẹ̀ jìnnà sí àwọn ènìyàn. Bí ó ṣe ti ilẹ̀ ni, nínú rẹ̀ ni oúnjẹ ti ń jáde wá, àti ohun tí ó wà ní ìsàlẹ̀ ni ó yí padà bi iná Òkúta ibẹ̀ ni ibi òkúta Safire, o sì ní erùpẹ̀ wúrà. Ipa ọ̀nà náà ni ẹyẹ kò mọ̀, àti ojú gúnnugún kò rí i rí; Àwọn ẹranko agbéraga kò rìn ibẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kìnnìún tí ń ké ramúramù kò kọjá níbẹ̀ rí. Ó fi ọwọ́ rẹ̀ lé akọ òkúta, ó yí òkè ńlá po láti ìdí rẹ̀ wá. Ó sì la ipa odò ṣíṣàn nínú àpáta, ojú inú rẹ̀ sì rí ohun iyebíye gbogbo. Ó sì ṣe ìṣàn odò kí ó má ṣe kún àkúnya, ó sì mú ohun tí ó pamọ́ hàn jáde wá sí ìmọ́lẹ̀. Ṣùgbọ́n níbo ni á ó gbé wá ọgbọ́n rí, níbo sì ni òye ń gbe? Ènìyàn kò mọ iye rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è rí i ní ilẹ̀ àwọn alààyè. Ọ̀gbun wí pé, “Kò sí nínú mi”; omi Òkun sì wí pé, “Kò si nínú mi.” A kò le è fi wúrà rà á, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi òṣùwọ̀n wọn fàdákà ní iye rẹ̀. A kò le è fi wúrà ofiri, tàbí òkúta óníkìsì iyebíye, tàbí òkúta Safire díye lé e. Wúrà àti òkúta kristali kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le è fi ohun èlò wúrà ṣe pàṣípàrọ̀ rẹ̀. A kò lè dárúkọ iyùn tàbí òkúta jasperi; iye ọgbọ́n sì ju iyùn lọ. Òkúta topasi ti Kuṣi kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni a kò le fi wúrà dáradára díwọ̀n iye rẹ̀. Níbo ha ni ọgbọ́n ti jáde wá? Tàbí níbo ni òye ń gbé? A rí i pé, ó fi ara sinko kúrò ní ojú àwọn alààyè gbogbo, ó sì fi ara sin fún ẹyẹ ojú ọ̀run. Ibi ìparun àti ikú wí pé, àwa ti fi etí wa gbúròó rẹ̀. Ọlọ́run ni ó mọ òye ipa ọ̀nà rẹ̀, òun ni ó sì mọ ibi tí ó ń gbé. Nítorí pé ó wòye dé òpin ayé, ó sì rí gbogbo ìsàlẹ̀ ọ̀run, Láti dà òṣùwọ̀n fún afẹ́fẹ́, ó sì fi òṣùwọ̀n wọ́n omi. Nígbà tí ó pàṣẹ fún òjò, tí ó sì la ọ̀nà fún mọ̀nàmọ́ná àrá, Nígbà náà ni ó rí i, ó sì sọ ọ́ jáde; ó pèsè rẹ̀ sílẹ̀, ó sì ṣe ìwádìí rẹ̀ rí. Àti fún ènìyàn ni ó wí pé, “Kíyèsi i, ẹ̀rù Olúwa èyí ni ọgbọ́n, àti láti jáde kúrò nínú ìwà búburú èyí ni òye.”