Job 28:1-28

Job 28:1-28 YBCV

NITOTỌ ipa-ilẹ fàdaka mbẹ, ati ibi ti nwọn a ma idà wura. Ninu ilẹ li a gbe nwà irin, bàba li a si ndà lati inu okuta wá. Enia li o pari òkunkun, o si ṣe awari okuta òkunkun ati ti inu ojiji ikú si iha gbogbo. Nwọn wá iho ilẹ ti o jìn si awọn ti o ngbe oke, awọn ti ẹsẹ enia gbagbe nwọn rọ si isalẹ, nwọn rọ si isalẹ jina si awọn enia. Bi o ṣe ti ilẹ ni, ninu rẹ̀ ni onjẹ ti ijade wá, ati ohun ti o wà nisalẹ li o yi soke bi ẹnipe iná. Okuta ibẹ ni ibi okuta Safiri, o si ni erupẹ wura. Ipa ọ̀na na ni ẹiyẹ kò mọ̀, ati oju gunugun kò ri i ri. Awọn ọmọ kiniun kò rin ibẹ rí, bẹ̃ni kiniun ti nké ramuramu kò kọja nibẹ rí. O fi ọwọ rẹ̀ le akọ apata, o yi oke-nla po lati idi rẹ̀ wá. O si la ipa-odò ṣiṣàn ninu apata, oju rẹ̀ si ri ohun iyebiye gbogbo. O si sé iṣàn odò ki o má ṣe kún akunya, o si mu ohun ti o lumọ hàn jade wá si imọlẹ. Ṣugbọn nibo li a o gbe wá ọgbọ́n ri, nibo si ni ibi oye? Enia kò mọ̀ iye rẹ̀, bẹ̃li a kò le iri i ni ilẹ awọn alãyè. Ọgbun wipe, kò si ninu mi, omi-okun si wipe, kò si ninu mi. A kò le fi wura rà a, bẹ̃li a kò le ifi òṣuwọn wọ̀n fadaka ni iye rẹ̀. A kò le fi wura Ofiri diyele e, pẹlu okuta oniksi iyebiye, ati okuta Safiri. Wura ati okuta kristali kò to ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le fi ohun èlo wura ṣe paṣiparọ rẹ̀. A kò le idarukọ iyun tabi okuta perli; iye ọgbọ́n si jù okuta rubi lọ. Okuta topasi ti Etiopia kò tó ẹgbẹ́ rẹ̀, bẹ̃li a kò le ifi wura daradara diye le e. Nibo ha li ọgbọn ti jade wá; tabi nibo ni ibi oye? A ri pe, o lumọ kuro li oju awọn alãyè gbogbo, o si fara sin fun ẹiyẹ oju ọrun. Ibi iparun (Abaddoni) ati ikú wipe, Awa ti fi etí wa gburo rẹ̀. Ọlọrun li o moye ipa ọ̀na rẹ̀, o si mọ̀ ipo rẹ̀, Nitoripe o woye de opin aiye, o si ri gbogbo isalẹ ọrun. Lati dà òṣuwọn fun afẹfẹ, o si fi òṣuwọn wọ̀n omiyomi. Nigbati o paṣẹ fun òjo, ti o si la ọ̀na fun mànamana ãrá: Nigbana li o ri i, o si sọ ọ jade, o pèse rẹ̀ silẹ, ani o si wadi rẹ̀ ri. Ati fun enia li o wipe, kiyesi i; Ẹru Oluwa, eyi li ọgbọ́n, ati lati jade kuro ninu ìwa-buburu eyi li oye!