Jer 33:1-13

Jer 33:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá lẹ̃keji, nigbati a si se e mọ ninu agbala ile túbu, wipe, Bayi li Oluwa wi, ẹniti o ṣe e, Oluwa, ti o pinnu rẹ̀, lati fi idi rẹ̀ mulẹ; Oluwa li orukọ rẹ̀; Képe mi, emi o si da ọ lohùn, emi o si fi ohun nla ati alagbara han ọ ti iwọ kò mọ̀. Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ile ilu yi, ati niti ile awọn ọba Juda ti a wó lulẹ ati nitori odi ati nitori idà; Nwọn wá lati ba awọn ara Kaldea jà, ṣugbọn lati fi okú enia kún wọn, awọn ẹniti Emi pa ninu ibinu mi ati ninu irunu mi, ati nitori gbogbo buburu wọnni, nitori eyiti emi ti pa oju mi mọ fun ilu yi. Wò o, emi o fi ọjá ati õgùn imularada dì i, emi o si wò wọn san, emi o si fi ọ̀pọlọpọ alafia ati otitọ hàn fun wọn. Emi o si mu igbèkun Juda ati igbèkun Israeli pada wá, emi o si gbe wọn ró gẹgẹ bi ti iṣaju. Emi o si wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo aiṣedede wọn, nipa eyiti nwọn ti ṣẹ̀ si mi; emi o si dari gbogbo aiṣedede wọn jì nipa eyiti nwọn ti sẹ̀, ati nipa eyi ti nwọn ti ṣe irekọja si mi. Ilu na yio si jẹ orukọ ayọ̀ fun mi, iyìn ati ọlá niwaju gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye, ti nwọn gbọ́ gbogbo rere ti emi ṣe fun wọn: nwọn o si bẹ̀ru, nwọn o si warìri, nitori gbogbo ore ati nitori gbogbo alafia ti emi ṣe fun u. Bayi li Oluwa wi; A o si tun gbọ́ ni ibi yi ti ẹnyin wipe, O dahoro, laini enia ati laini ẹran, ani ni ilu Juda, ati ni ilu Jerusalemu, ti o dahoro, laini enia, ati laini olugbe, ati laini ẹran. Ohùn ayọ̀, ati ohùn inu-didùn, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, ohùn awọn ti o wipe, Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn ọmọ-ogun: nitori ti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai: ati ti awọn ti o mu ẹbọ-ọpẹ́ wá si ile Oluwa. Nitoriti emi o mu igbèkun ilẹ na pada wá gẹgẹ bi atetekọṣe, li Oluwa wi. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Papa-oko awọn oluṣọ-agutan yio tun wà, ti nwọn mu ẹran-ọsin dubulẹ ni ibi yi, ti o dahoro, laini enia ati laini ẹran, ati ni gbogbo ilu rẹ̀! Ninu ilu oke wọnni, ninu ilu afonifoji, ati ninu ilu iha gusu, ati ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda ni agbo agutan yio ma kọja labẹ ọwọ ẹniti nkà wọn, li Oluwa wi.

Jer 33:1-13 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA bá Jeremaya sọ̀rọ̀ lẹẹkeji, nígbà tí ó ṣì wà ní ẹ̀wọ̀n, ní àgbàlá àwọn tí ń ṣọ́ ààfin. OLUWA tí ó dá ayé, tí ó sì fìdí rẹ̀ múlẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ OLUWA, ni ó sọ pé: “Ẹ ké pè mí, n óo sì da yín lóhùn; n óo sọ nǹkan ìjìnlẹ̀ ati ìyanu ńlá, tí ẹ kò mọ̀ tẹ́lẹ̀ fun yín.” OLUWA, Ọlọrun Israẹli sọ nípa àwọn ilé tí wọ́n wà ní ìlú yìí, ati ilé ọba Juda, àwọn tí wọn dótì wá, tí wọn ń gbógun tì wá yóo wó wọn lulẹ̀ Ó ní, “Àwọn ará Kalidea ń gbógun bọ̀, wọn yóo da òkú àwọn eniyan tí n óo fi ibinu ati ìrúnú pa kún àwọn ilé tí ó wà ní ìlú yìí, nítorí mo ti fi ara pamọ́ fún ìlú yìí nítorí gbogbo ìwà burúkú wọn. N óo mú ìlera ati ìwòsàn wá bá wọn; n óo wò wọ́n sàn, n óo sì fún wọn ní ọpọlọpọ ibukun ati ìfọ̀kànbalẹ̀. N óo dá ire Juda ati ti Israẹli pada, n óo sì tún wọn kọ́, wọn yóo dàbí wọ́n ti rí lákọ̀ọ́kọ́. N óo wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu gbogbo ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá sí mi, n óo dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ati oríkunkun tí wọ́n ṣe sí mi jì wọ́n. Orúkọ ìlú yìí yóo sì jẹ́ orúkọ ayọ̀ fún mi, yóo jẹ́ ohun ìyìn ati ògo níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé tí yóo gbọ́ nípa nǹkan rere tí n óo ṣe fún wọn; ẹ̀rù yóo bà wọ́n, wọn yóo sì wárìrì, nítorí gbogbo nǹkan rere tí n óo máa ṣe fún ìlú náà.” OLUWA ní, “A óo tún gbọ́ ohùn ayọ̀ ati inú dídùn ninu ìlú Juda ati ìgboro Jerusalẹmu, tí ẹ sọ wí pé ó ti di ahoro, tí kò sí eniyan tabi ẹranko tó ń gbé inú wọn. A óo tún gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ohùn iyawo ati ohùn àwọn tí wọn ń kọrin bí wọ́n ti ń mú ẹbọ ọpẹ́ wá sinu ilé OLUWA wí pé: 107:1; 118:1; 136:1 ‘Ẹ fi ọpẹ́ fún OLUWA àwọn ọmọ ogun, nítorí pé rere ni OLUWA, nítorí pé ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ wà títí lae!’ Nítorí pé n óo dá ire wọn pada bíi ti ìgbà àtijọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.” OLUWA àwọn ọmọ ogun sọ pé, “Ní gbogbo ibi tí ó ti di ahoro yìí, tí eniyan tabi ẹranko kò gbé ibẹ̀, àwọn olùṣọ́-aguntan yóo sì tún máa tọ́jú àwọn agbo ẹran wọn ninu gbogbo àwọn ìlú ibẹ̀. Àwọn agbo ẹran yóo tún kọjá níwájú ẹni tí ó ń kà wọ́n ninu àwọn ìlú tí wọ́n wà ní agbègbè olókè, ati àwọn ti pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela ati àwọn ìlú tí wọn wà ní Nẹgẹbu, ní ilẹ̀ Bẹnjamini, ní agbègbè tí ó yí Jerusalẹmu ká, ati àwọn ìlú Juda. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Jer 33:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí Jeremiah wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì: “Èyí ni ohun tí OLúWA sọ, ẹni tí ó dá ayé, OLúWA tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, OLúWA ni orúkọ rẹ̀: ‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’ Nítorí èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn ọba Juda tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà nínú ìjà pẹ̀lú Kaldea: ‘Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi. Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn. “ ‘Wò ó, èmi ó mú ọ̀já àti oògùn ìmúláradá dì í; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn lọ́pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́. Èmi ó mú Juda àti Israẹli kúrò nínú ìgbèkùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀. Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sí mi. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedéédéé wọn sí mi jì wọ́n. Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèsè fún wọn.’ “Èyí ni ohun tí OLúWA wí, ‘Ẹ̀yin yóò wí nípa ibí yìí pé, “Ó dahoro, láìsí ènìyàn tàbí ẹran.” Síbẹ̀ ní ìlú Juda àti ní òpópónà Jerusalẹmu tí ó dahoro, láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; ìbá à se ènìyàn tàbí ẹran, tí yóò gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí. Ariwo ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé OLúWA wí pé: “ ‘ “Yin OLúWA àwọn ọmọ-ogun, nítorí OLúWA dára, ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.” Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀,’ ni OLúWA wí: “Èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi. Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú Àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni OLúWA wí.