Jer 33

33
Ìlérí Ìrètí Mìíràn
1Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá lẹ̃keji, nigbati a si se e mọ ninu agbala ile túbu, wipe,
2Bayi li Oluwa wi, ẹniti o ṣe e, Oluwa, ti o pinnu rẹ̀, lati fi idi rẹ̀ mulẹ; Oluwa li orukọ rẹ̀;
3Képe mi, emi o si da ọ lohùn, emi o si fi ohun nla ati alagbara han ọ ti iwọ kò mọ̀.
4Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ile ilu yi, ati niti ile awọn ọba Juda ti a wó lulẹ ati nitori odi ati nitori idà;
5Nwọn wá lati ba awọn ara Kaldea jà, ṣugbọn lati fi okú enia kún wọn, awọn ẹniti Emi pa ninu ibinu mi ati ninu irunu mi, ati nitori gbogbo buburu wọnni, nitori eyiti emi ti pa oju mi mọ fun ilu yi.
6Wò o, emi o fi ọjá ati õgùn imularada dì i, emi o si wò wọn san, emi o si fi ọ̀pọlọpọ alafia ati otitọ hàn fun wọn.
7Emi o si mu igbèkun Juda ati igbèkun Israeli pada wá, emi o si gbe wọn ró gẹgẹ bi ti iṣaju.
8Emi o si wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo aiṣedede wọn, nipa eyiti nwọn ti ṣẹ̀ si mi; emi o si dari gbogbo aiṣedede wọn jì nipa eyiti nwọn ti sẹ̀, ati nipa eyi ti nwọn ti ṣe irekọja si mi.
9Ilu na yio si jẹ orukọ ayọ̀ fun mi, iyìn ati ọlá niwaju gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye, ti nwọn gbọ́ gbogbo rere ti emi ṣe fun wọn: nwọn o si bẹ̀ru, nwọn o si warìri, nitori gbogbo ore ati nitori gbogbo alafia ti emi ṣe fun u.
10Bayi li Oluwa wi; A o si tun gbọ́ ni ibi yi ti ẹnyin wipe, O dahoro, laini enia ati laini ẹran, ani ni ilu Juda, ati ni ilu Jerusalemu, ti o dahoro, laini enia, ati laini olugbe, ati laini ẹran.
11Ohùn ayọ̀, ati ohùn inu-didùn, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, ohùn awọn ti o wipe, Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn ọmọ-ogun: nitori ti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai: ati ti awọn ti o mu ẹbọ-ọpẹ́ wá si ile Oluwa. Nitoriti emi o mu igbèkun ilẹ na pada wá gẹgẹ bi atetekọṣe, li Oluwa wi.
12Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Papa-oko awọn oluṣọ-agutan yio tun wà, ti nwọn mu ẹran-ọsin dubulẹ ni ibi yi, ti o dahoro, laini enia ati laini ẹran, ati ni gbogbo ilu rẹ̀!
13Ninu ilu oke wọnni, ninu ilu afonifoji, ati ninu ilu iha gusu, ati ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda ni agbo agutan yio ma kọja labẹ ọwọ ẹniti nkà wọn, li Oluwa wi.
14Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu ohun rere na, ti emi ti leri fun ilẹ Israeli ati fun ile Juda, ṣẹ.
15Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, emi o jẹ ki Ẹka ododo ki o hu soke fun Dafidi; ẹniti yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.
16Li ọjọ wọnni li a o gbà Juda la, Jerusalemu yio si ma gbe li ailewu: orukọ yi li a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.
17Nitori bayi li Oluwa wi; A kì o fẹ ọkunrin kan kù lọdọ Dafidi lati joko lori itẹ́ ile Israeli lailai.
18Bẹ̃ni awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, kì yio fẹ ọkunrin kan kù niwaju mi lati ru ẹbọ sisun, ati lati dana ọrẹ ohun jijẹ, ati lati ṣe irubọ lojojumọ.
19Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá, wipe,
20Bayi li Oluwa wi; Bi ẹnyin ba le bà majẹmu mi ti ọsan jẹ, ati majẹmu mi ti oru, tí ọsan ati oru kò le si li akoko wọn;
21Nigbana ni majẹmu mi pẹlu Dafidi, iranṣẹ mi le bajẹ, pe ki on ki o má le ni ọmọ lati joko lori itẹ rẹ̀; ati pẹlu awọn ọmọ Lefi, awọn alufa, awọn iranṣẹ mi.
22Gẹgẹ bi a kò ti le ka iye ogun-ọrun, tabi ki a le wọ̀n iyanrin eti okun: bẹ̃ni emi o sọ iru-ọmọ Dafidi iranṣẹ mi di pupọ, ati awọn ọmọ Lefi, ti nṣe iranṣẹ fun mi.
23Ọ̀rọ Oluwa si tọ Jeremiah wá, wipe,
24Iwọ kò ha ro eyi ti awọn enia yi ti sọ wipe, Idile meji ti Oluwa ti yàn, o ti kọ̀ wọn silẹ̀? nitorina ni nwọn ti ṣe kẹgan awọn enia mi, pe nwọn kì o le jẹ orilẹ-ède kan mọ li oju wọn.
25Bayi li Oluwa wi, Bi emi kò ba paṣẹ majẹmu mi ti ọsan ati ti oru, pẹlu ilana ọrun ati aiye,
26Nigbana ni emi iba ta iru-ọmọ Jakobu nù, ati Dafidi, iranṣẹ mi, ti emi kì o fi mu ninu iru-ọmọ rẹ̀ lati ṣe alakoso lori iru-ọmọ Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu: nitori emi o mu ki igbekun wọn ki o pada bọ̀, emi o si ṣãnu fun wọn.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jer 33: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa