Jeremiah 33:1-13

Jeremiah 33:1-13 YCB

Nígbà tí Jeremiah wà nínú àgbàlá túbú, ọ̀rọ̀ OLúWA tọ̀ ọ́ wá lẹ́ẹ̀kejì: “Èyí ni ohun tí OLúWA sọ, ẹni tí ó dá ayé, OLúWA tí ó mọ ayé tí ó sì fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, OLúWA ni orúkọ rẹ̀: ‘Pè mí, èmi ó sì dá ọ lóhùn, èmi ó sì sọ ohun alágbára ńlá àti ọ̀pọ̀ ohun tí kò ṣe é wádìí tí ìwọ kò mọ̀ fún ọ.’ Nítorí èyí ni ohun tí OLúWA Ọlọ́run àwọn Israẹli sọ nípa àwọn ilẹ̀ ìlú yìí àti ààfin àwọn ọba Juda tí ó ti wó lulẹ̀ nítorí àwọn ìdọ̀tí àti idà nínú ìjà pẹ̀lú Kaldea: ‘Wọn yóò kún fún ọ̀pọ̀ òkú ọmọkùnrin tí èmi yóò pa nínú ìbínú àti nínú ìrunú mi. Èmi ó pa ojú mi mọ́ kúrò ní ìlú yìí nítorí gbogbo búburú wọn. “ ‘Wò ó, èmi ó mú ọ̀já àti oògùn ìmúláradá dì í; èmi ó wo àwọn ènìyàn mi sàn. Èmi ó sì jẹ́ kí wọn ó jẹ ìgbádùn lọ́pọ̀lọpọ̀ àlàáfíà àti òtítọ́. Èmi ó mú Juda àti Israẹli kúrò nínú ìgbèkùn, èmi ó sì tún wọn kọ́ gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀. Èmi ó wẹ̀ wọ́n nù kúrò nínú gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ti ṣẹ sí mi. Èmi ó sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àìṣedéédéé wọn sí mi jì wọ́n. Nígbà náà ni ìlú yìí ó fún mi ní òkìkí, ayọ̀, ìyìn àti ọlá níwájú gbogbo orílẹ̀-èdè ayé; tí wọ́n gbọ́ gbogbo rere tí èmi ṣe fún wọn. Wọn ó sì bẹ̀rù, wọn ó wárìrì fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oore àti àlàáfíà tí èmi pèsè fún wọn.’ “Èyí ni ohun tí OLúWA wí, ‘Ẹ̀yin yóò wí nípa ibí yìí pé, “Ó dahoro, láìsí ènìyàn tàbí ẹran.” Síbẹ̀ ní ìlú Juda àti ní òpópónà Jerusalẹmu tí ó dahoro, láìsí ẹni tó gbé ibẹ̀; ìbá à se ènìyàn tàbí ẹran, tí yóò gbọ́ lẹ́ẹ̀kan sí. Ariwo ayọ̀ àti inú dídùn, ohùn ìyàwó àti ti ọkọ ìyàwó àti ohùn àwọn tí ó ru ẹbọ ọpẹ́ wọn nílé OLúWA wí pé: “ ‘ “Yin OLúWA àwọn ọmọ-ogun, nítorí OLúWA dára, ìfẹ́ rẹ̀ dúró títí láéláé.” Nítorí èmi ó dá ìkólọ ilẹ̀ náà padà sí bí o ṣe wà tẹ́lẹ̀,’ ni OLúWA wí: “Èyí ni ohun tí OLúWA àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ní ilẹ̀ yìí tí ó ti dahoro láìsí ọkùnrin àti àwọn ẹran nínú gbogbo ìlú, kò ní sí pápá oko fún àwọn olùṣọ́-àgùntàn láti mú àwọn ẹran ọ̀sìn wọn sinmi. Ní ìlú òkè wọ̀n-ọn-nì, nínú ìlú Àfonífojì, àti nínú ìlú ìhà gúúsù, àti ní ilẹ̀ ti Benjamini, ní ibi wọ̀n-ọn-nì tí ó yí Jerusalẹmu ká, àti ní ìlú Juda ni agbo àgùntàn yóò tún máa kọjá ní ọwọ́ ẹni tí ń kà wọ́n,’ ni OLúWA wí.