Jer 15:18-20
Jer 15:18-20 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẽṣe ti irora mi pẹ́ titi, ati ọgbẹ mi jẹ alaiwotan, ti o kọ̀ lati jina? lõtọ iwọ si dabi kanga ẹ̀tan fun mi, bi omi ti kò duro? Nitorina, bayi li Oluwa wi, Bi iwọ ba yipada, nigbana li emi o si tun mu ọ pada wá, iwọ o si duro niwaju mi: bi iwọ ba si yà eyi ti iṣe iyebiye kuro ninu buburu, iwọ o dabi ẹnu mi: nwọn o si yipada si ọ; ṣugbọn iwọ máṣe yipada si wọn. Emi o si ṣe ọ fun awọn enia yi bi odi idẹ ati alagbara: nwọn o si ba ọ jà, ṣugbọn nwọn kì yio le bori rẹ, nitori emi wà pẹlu rẹ, lati gbà ọ là ati lati gbà ọ silẹ, li Oluwa wi.
Jer 15:18-20 Yoruba Bible (YCE)
Kí ló dé tí ìrora mi kò dáwọ́ dúró, tí ọgbẹ́ mi jinlẹ̀, tí ó kọ̀, tí kò san? Ṣé o fẹ́ dá mi lọ́kàn le lásán ni; bí ẹlẹ́tàn odò tíí gbẹ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn?” Nítorí náà OLUWA ní, “Bí o bá yipada, n óo mú ọ pada sípò rẹ, o óo sì tún máa ṣe iranṣẹ mi. Bí o bá bẹ̀rẹ̀ sí sọ ọ̀rọ̀ gidi, tí o dákẹ́ ìsọkúsọ, o óo tún pada di òjíṣẹ́ mi. Àwọn ni yóo pada tọ̀ ọ́ wá, o kò ní tọ̀ wọ́n lọ. N óo sọ ọ́ di odi alágbára tí a fi idẹ mọ, lọ́dọ̀ àwọn eniyan wọnyi. Wọn yóo gbógun tì ọ́, ṣugbọn wọn kò ní ṣẹgun rẹ, nítorí pé mo wà pẹlu rẹ láti gbà ọ́, ati láti yọ ọ́. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
Jer 15:18-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èéṣe tí ìrora mi kò lópin, tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn? Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi, gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun? Nítorí náà báyìí ni OLúWA wí: “Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di agbẹnusọ mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ; ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là, kí n sì dáàbò bò ọ́,” ni OLúWA wí.