Jer 15

15
Ìparun Yóo Dé Bá Àwọn Ọmọ Juda
1OLUWA si wi fun mi pe, Bi Mose ati Samueli duro niwaju mi, sibẹ inu mi kì yio si yipada si awọn enia yi: ṣá wọn tì kuro niwaju mi, ki nwọn o si jade lọ.
2Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, nibo ni awa o jade lọ? ki iwọ ki o sọ fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; awọn ti ikú, si ikú, awọn ti idà, si idà; ati awọn ti ìyan, si ìyan, ati awọn ti igbèkun si igbèkun.
3Emi si fi iru ijiya mẹrin sori wọn, li Oluwa wi, idà lati pa, ajá lati wọ́ kiri, ẹiyẹ oju-ọrun ati ẹranko ilẹ, lati jẹ, ati lati parun.
4Emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, nitori Manasse, ọmọ Hesekiah, ọba Juda, nitori eyiti o ti ṣe ni Jerusalemu.
5Nitori tani yio ṣãnu fun ọ, iwọ Jerusalemu? tabi ti yio sọkun rẹ? tabi tani yio wá lati bere alafia rẹ.
6Iwọ ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, iwọ ti pada sẹhin; nitorina emi o ná ọwọ mi si ọ, emi o si pa ọ run; ãrẹ̀ mu mi lati ṣe iyọnu.
7Emi o fi atẹ fẹ́ wọn si ẹnu-ọ̀na ilẹ na; emi o pa awọn ọmọ wọn, emi o si pa enia mi run, ẹniti kò yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀.
8Awọn opo rẹ̀ o di pipọ ju iyanrin eti okun: emi o mu arunni wa sori wọn, sori iyá ati ọdọmọkunrin li ọjọkanri; emi o mu ifoya ati ìbẹru nla ṣubu lu wọn li ojiji.
9Ẹniti o bi meje nṣọ̀fọ o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ; õrùn rẹ̀ wọ̀ l'ọsan, oju ntì i, o si ndamu: iyoku ninu wọn l'emi o si fifun idà niwaju awọn ọta wọn, li Oluwa wi.
Jeremiah Ráhùn sí OLUWA
10Egbe ni fun mi, iyá mi, ti o bi mi ni ọkunrin ija ati ijiyan gbogbo aiye! emi kò win li elé, bẹ̃ni enia kò win mi li elé; sibẹ gbogbo wọn nfi mi ré.
11Oluwa ni, Emi kì o tú ọ silẹ fun rere! emi o mu ki ọta ki o bẹ̀ ọ ni ìgba ibi ati ni ìgba ipọnju!
12A ha le ṣẹ irin, irin ariwa, ati idẹ bi?
13Ohun-ini ati iṣura rẹ li emi o fi fun ijẹ, li aigbowo, nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ ni àgbegbe rẹ.
14Emi o si mu ki awọn ọta rẹ kó wọn lọ si ilẹ ti iwọ kò mọ̀: nitoriti iná njo ni ibinu mi, ti yio jo lori rẹ.
15Oluwa, iwọ mọ̀, ranti mi, bẹ̀ mi wò, ki o si gbẹsan mi lara awọn oninunibini mi! máṣe mu mi kuro nitori ipamọra rẹ: mọ̀ pe, mo ti jiya itiju nitori rẹ!
16Nigbati a ri ọ̀rọ rẹ, emi si jẹ wọn, ọ̀rọ rẹ si jẹ inu didùn mi, nitori orukọ rẹ li a fi npè mi, iwọ Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun!
17Emi kò joko ni ajọ awọn ẹlẹgan! ki emi si ni ayọ̀; mo joko emi nikan, nitori ọwọ rẹ: nitori iwọ ti fi ibanujẹ kún mi.
18Ẽṣe ti irora mi pẹ́ titi, ati ọgbẹ mi jẹ alaiwotan, ti o kọ̀ lati jina? lõtọ iwọ si dabi kanga ẹ̀tan fun mi, bi omi ti kò duro?
19Nitorina, bayi li Oluwa wi, Bi iwọ ba yipada, nigbana li emi o si tun mu ọ pada wá, iwọ o si duro niwaju mi: bi iwọ ba si yà eyi ti iṣe iyebiye kuro ninu buburu, iwọ o dabi ẹnu mi: nwọn o si yipada si ọ; ṣugbọn iwọ máṣe yipada si wọn.
20Emi o si ṣe ọ fun awọn enia yi bi odi idẹ ati alagbara: nwọn o si ba ọ jà, ṣugbọn nwọn kì yio le bori rẹ, nitori emi wà pẹlu rẹ, lati gbà ọ là ati lati gbà ọ silẹ, li Oluwa wi.
21Emi o si gba ọ silẹ kuro lọwọ awọn enia buburu, emi o si rà ọ pada kuro lọwọ awọn ìka.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Jer 15: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa