Jer 12:1-4
Jer 12:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
ALARE ni iwọ, Oluwa, nigbati mo mba ọ wijọ: sibẹ, jẹ ki emi ba ọ sọ ti ọ̀ran idajọ: ẽtiṣe ti ãsiki mbẹ ni ọ̀na enia buburu, ti gbogbo awọn ti nṣe ẹ̀tan jẹ alailewu. Iwọ ti gbìn wọn, nwọn si ti ta gbòngbo: nwọn dagba, nwọn si nso eso: iwọ sunmọ ẹnu wọn, o si jìna si ọkàn wọn. Ṣugbọn iwọ, Oluwa, mọ̀ mi: iwọ ri mi, o si dan ọkàn mi wò bi o ti ri si ọ: pa wọn mọ bi agutan fun pipa, ki o si yà wọn sọtọ fun ọjọ pipa. Yio ti pẹ to ti ilẹ yio fi ma ṣọ̀fọ, ati ti ewe igbẹ gbogbo yio rẹ̀ nitori ìwa-buburu awọn ti mbẹ ninu rẹ̀? ẹranko ati ẹiyẹ nṣòfò nitori ti nwọn wipe, on kì o ri ẹ̀hin wa.
Jer 12:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Olódodo ni ọ́, OLUWA, nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́; sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ. Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú? O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò; wọ́n dàgbà, wọ́n so èso; orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ. Ṣugbọn ìwọ OLUWA mọ̀ mí, O rí mi, o sì ti yẹ ọkàn mi wò o mọ èrò mi sí ọ. Fà wọ́n jáde bí aguntan tí wọn ń mú lọ pa, yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìparun. Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀, tí koríko oko yóo rọ? Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé, nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.”
Jer 12:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
OLúWA, olódodo ni ọ́ nígbàkúgbà, nígbà tí mo mú ẹjọ́ kan tọ̀ ọ́ wá. Síbẹ̀ èmi yóò bá ọ sọ̀rọ̀ nípa òdodo rẹ. Èéṣe tí ọ̀nà àwọn ènìyàn búburú fi ń ṣe déédé? Èéṣe tí gbogbo àwọn aláìṣòdodo sì ń gbé ní ìrọ̀rùn? Ó ti gbìn wọ́n, wọ́n sì ti fi egbò múlẹ̀, wọ́n dàgbà wọ́n sì so èso. Gbogbo ìgbà ni ó wà ní ètè wọn, o jìnnà sí ọkàn wọn. Síbẹ̀ o mọ̀ mí ní OLúWA, o ti rí mi o sì ti dán èrò mi nípa rẹ wò. Wọ, wọ́n lọ bí àgùntàn tí a fẹ́ pa. Yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ pípa. Yóò ti pẹ́ tó tí ọ̀gbẹlẹ̀ yóò fi wà, tí gbogbo ewéko igbó sì ń rọ? Nítorí àwọn ènìyàn búburú ni ó ń gbé ibẹ̀. Àwọn ẹranko àti àwọn ẹyẹ ti ṣègbé, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ènìyàn ń sọ pé, “Kò lè rí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa.”