Jer 12
12
1ALARE ni iwọ, Oluwa, nigbati mo mba ọ wijọ: sibẹ, jẹ ki emi ba ọ sọ ti ọ̀ran idajọ: ẽtiṣe ti ãsiki mbẹ ni ọ̀na enia buburu, ti gbogbo awọn ti nṣe ẹ̀tan jẹ alailewu.
2Iwọ ti gbìn wọn, nwọn si ti ta gbòngbo: nwọn dagba, nwọn si nso eso: iwọ sunmọ ẹnu wọn, o si jìna si ọkàn wọn.
3Ṣugbọn iwọ, Oluwa, mọ̀ mi: iwọ ri mi, o si dan ọkàn mi wò bi o ti ri si ọ: pa wọn mọ bi agutan fun pipa, ki o si yà wọn sọtọ fun ọjọ pipa.
4Yio ti pẹ to ti ilẹ yio fi ma ṣọ̀fọ, ati ti ewe igbẹ gbogbo yio rẹ̀ nitori ìwa-buburu awọn ti mbẹ ninu rẹ̀? ẹranko ati ẹiyẹ nṣòfò nitori ti nwọn wipe, on kì o ri ẹ̀hin wa.
5Bi iwọ ba ba ẹlẹsẹ rìn, ti ãrẹ si mu ọ, iwọ o ha ti ṣe ba ẹlẹṣin dije? ati pẹlu ni ilẹ alafia, bi iwọ ba ni igbẹkẹle, kini iwọ o ṣe ninu ẹkún odò Jordani?
6Nitori pẹlupẹlu, awọn arakunrin rẹ, ati ile baba rẹ, awọn na ti hùwa ẹ̀tan si ọ, lõtọ, awọn na ti ho le ọ: Má gbẹkẹle wọn, bi nwọn tilẹ ba ọ sọ̀rọ daradara.
OLUWA Káàánú Àwọn Eniyan Rẹ̀
7Emi ti kọ̀ ile mi silẹ, mo ti fi ogún mi silẹ; mo ti fi olufẹ ọ̀wọn ọkàn mi le ọta rẹ̀ lọwọ.
8Ogún mi di kiniun ninu igbo fun mi; on kigbe soke si mi; nitorina ni mo ṣe korira rẹ̀.
9Ogún mi di ẹranko ọ̀wawa fun mi, ẹranko yi i kakiri, ẹ lọ, ẹ ko gbogbo ẹran igbẹ jọ pọ̀, ẹ mu wọn wá jẹ.
10Ọ̀pọlọpọ oluṣọ-agutan ba ọgba ajara mi jẹ, nwọn tẹ ipin oko mi mọlẹ labẹ ẹsẹ wọn, nwọn ti sọ ipin oko mi ti mo fẹ di aginju ahoro.
11Nwọn ti sọ ọ di ahoro, o ṣọ̀fọ fun mi bi ahoro: gbogbo ilẹ ti di ahoro, nitori ti kò si ẹnikan ti o rò li ọkàn rẹ̀.
12Awọn abanijẹ ti gori gbogbo ibi giga wọnni ni ọ̀dan, nitori idà Oluwa yio pa lati ikangun de ikangun ekeji ilẹ na, alafia kò si fun gbogbo alãye.
13Nwọn ti gbin alikama, ṣugbọn nwọn o ka ẹ́gun, nwọn ti fi irora ẹ̀dun mu ara wọn, ṣugbọn nwọn kì yio ri anfani: ki oju ki o tì nyin nitori ère nyin, nitori ibinu gbigbona Oluwa.
Ìlérí OLUWA fún Àwọn Aládùúgbò Israẹli
14Bayi li Oluwa wi si gbogbo awọn aladugbo buburu mi ti nwọn fi ọwọ kan ogún mi ti mo ti mu enia mi, Israeli, jogun. Sa wò o, emi o fa wọn tu kuro ni ilẹ wọn, emi o si fà ile Juda tu kuro larin wọn.
15Yio si ṣe, nigba ti emi o ti fà wọn tu kuro tan, emi o pada, emi o si ni iyọ́nu si wọn, emi o si tun mu wọn wá, olukuluku wọn, si ogún rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀.
16Yio si ṣe, bi nwọn ba ṣe ãpọn lati kọ́ ìwa enia mi, lati fi orukọ mi bura pe, Oluwa mbẹ: gẹgẹ bi nwọn ti kọ́ enia mi lati fi Baali bura; nigbana ni a o gbe wọn ró lãrin enia mi.
17Ṣugbọn bi nwọn kì o gbọ́, emi o fà orilẹ-ède na tu patapata; emi o si pa wọn run, li Oluwa wi.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Jer 12: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.