JEREMAYA 12:1-4

JEREMAYA 12:1-4 YCE

Olódodo ni ọ́, OLUWA, nígbà tí mo bá ń fẹjọ́ sùn ọ́; sibẹ n óo ro ẹjọ́ mi níwájú rẹ. Kí ló dé tí nǹkan ń dára fún àwọn eniyan burúkú? O gbìn wọ́n, wọ́n ta gbòǹgbò; wọ́n dàgbà, wọ́n so èso; orúkọ rẹ kò jìnnà sẹ́nu wọn, ṣugbọn ọkàn wọn jìnnà sí ọ. Ṣugbọn ìwọ OLUWA mọ̀ mí, O rí mi, o sì ti yẹ ọkàn mi wò o mọ èrò mi sí ọ. Fà wọ́n jáde bí aguntan tí wọn ń mú lọ pa, yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ọjọ́ ìparun. Yóo ti pẹ́ tó, tí ilẹ̀ náà yóo máa ṣọ̀fọ̀, tí koríko oko yóo rọ? Nítorí iṣẹ́ burúkú àwọn tí wọn ń gbé inú rẹ̀, àwọn ẹranko ati àwọn ẹyẹ ṣègbé, nítorí àwọn eniyan ń wí pé, “Kò ní rí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ sí wa.”