A. Oni 8:18-35

A. Oni 8:18-35 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana li o sọ fun Seba ati Salmunna, wipe, Irú ọkunrin wo li awọn ẹniti ẹnyin pa ni Taboru? Nwọn si dahùn, Bi iwọ ti ri, bẹ̃ni nwọn ri; olukuluku nwọn dabi awọn ọmọ ọba. On si wipe, Arakunrin mi ni nwọn, ọmọ iya mi ni nwọn iṣe: bi OLUWA ti wà, ibaṣepe ẹnyin da wọn si, emi kì ba ti pa nyin. On si wi fun Jeteri arẹmọ rẹ̀ pe, Dide, ki o si pa wọn. Ṣugbọn ọmọkunrin na kò fà idà rẹ̀ yọ: nitori ẹ̀ru bà a, nitoripe ọmọde ni iṣe. Nigbana ni Seba ati Salmunna wipe, Iwọ dide, ki o si kọlù wa: nitoripe bi ọkunrin ti ri, bẹ̃li agbara rẹ̀ ri. Gideoni si dide, o si pa Seba ati Salmunna, o si bọ́ ohun ọṣọ́ wọnni kuro li ọrùn ibakasiẹ wọn. Nigbana li awọn ọkunrin Israeli wi fun Gideoni pe, Iwọ ma ṣe olori wa, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ pẹlu: nitoripe o gbà wa lọwọ awọn ara Midiani. Gideoni si wi fun wọn pe, Emi ki yio ṣe olori nyin, bẹ̃ni ọmọ mi ki yio ṣe olori nyin: OLUWA ni yio ma ṣe alaṣẹ nyin. Gideoni si wi fun wọn pe, Emi o bère nkan lọwọ nyin, pe ki olukuluku nyin ki o le fi oruka-etí ti mbẹ ninu ikogun rẹ̀ fun mi. (Nitoriti nwọn ní oruka-etí ti wurà, nitoripe ọmọ Iṣmaeli ni nwọn iṣe.) Nwọn si dahùn wipe, Tinutinu li awa o fi mú wọn wá. Nwọn si tẹ́ aṣọ kan, olukuluku nwọn si sọ oruka-etí ikogun rẹ̀ si i. Ìwọn oruka-etí wurà na ti o bère lọwọ wọn jẹ́ ẹdẹgbẹsan ṣekeli wurà: làika ohun ọṣọ́ wọnni, ati ohun sisorọ̀, ati aṣọ elesè-àluko ti o wà lara awọn ọba Midiani, ati li àika ẹ̀wọn ti o wà li ọrùn ibakasiẹ wọn. Gideoni si fi i ṣe ẹ̀wu-efodu kan, o si fi i si ilu rẹ̀, ni Ofra: gbogbo Israeli si ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin nibẹ̀: o si wa di idẹkun fun Gideoni, ati fun ile rẹ̀. Bẹ̃li a si tẹ̀ ori Midiani ba niwaju awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si gbé ori wọn soke mọ́. Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún li ọjọ́ Gideoni. Jerubbaali ọmọ Joaṣi si lọ o si ngbe ile rẹ̀. Gideoni si ní ãdọrin ọmọkunrin ti o bi fun ara rẹ̀: nitoripe o lí obinrin pupọ̀. Ale rẹ̀ ti o wà ni Ṣekemu, on pẹlu bi ọmọkunrin kan fun u, orukọ ẹniti a npè ni Abimeleki. Gideoni ọmọ Joaṣi si kú li ọjọ́ ogbó, a si sin i si ibojì Joaṣi baba rẹ̀, ni Ofra ti awọn Abieseri. O si ṣe, lojukanna ti Gideoni kú, li awọn ọmọ Israeli pada, nwọn si ṣe panṣaga tọ̀ Baalimu lọ, nwọn si fi Baaliberiti ṣe oriṣa wọn. Awọn ọmọ Israeli kò si ranti OLUWA Ọlọrun wọn, ẹniti o gbà wọn lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn ni ìha gbogbo: Bẹ̃ni nwọn kò si ṣe ore fun ile Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, gẹgẹ bi gbogbo ire ti o ti ṣe fun Israeli.

A. Oni 8:18-35 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn náà, ó bi Seba ati Salimuna pé, “Níbo ni àwọn ọkunrin tí ẹ pa ní Tabori wà?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Bí o ti rí gan-an ni ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn náà rí, gbogbo wọn dàbí ọmọ ọba.” Ó dáhùn, ó ní, “Arakunrin mi ni wọ́n, ìyá kan náà ni ó bí wa. Bí OLUWA ti wà láàyè, bí ó bá jẹ́ pé ẹ dá wọn sí ni, ǹ bá dá ẹ̀yin náà sí.” Ó bá pe Jeteri àkọ́bí rẹ̀, ó ní, “Dìde, kí o sì pa wọ́n,” ṣugbọn ọmọ náà kò fa idà rẹ̀ yọ nítorí pé ẹ̀rù ń bà á, nítorí ọmọde ni. Seba ati Salimuna bá dáhùn pé, “Ìwọ alára ni kí o dìde kí o pa wá? Ṣebí bí ọkunrin bá ṣe dàgbà sí ni yóo ṣe lágbára sí.” Gideoni bá dìde, ó pa Seba ati Salimuna, ó sì bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn ràkúnmí wọn. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ Israẹli wí fún Gideoni pé, “Máa jọba lórí wa, ìwọ ati ọmọ rẹ, ati àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹlu, nítorí pé ìwọ ni o gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.” Gideoni dá wọn lóhùn, ó ní “N kò ní jọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni ọmọ mi kò ní jọba lórí yín, OLUWA ni yóo máa jọba lórí yín.” Ṣugbọn ó rọ̀ wọ́n pé kí olukuluku wọn fún òun ní yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀, nítorí pé àwọn ará Midiani a máa lo yẹtí wúrà gẹ́gẹ́ bí àwọn ará ilẹ̀ Iṣimaeli yòókù. Wọ́n dá a lóhùn pé, “A óo fi tayọ̀tayọ̀ kó wọn fún ọ.” Wọ́n bá tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀, olukuluku sì bẹ̀rẹ̀ sí ju yẹtí tí ó wà ninu ìkógun rẹ̀ sibẹ. Gbogbo ìwọ̀n yẹtí wúrà tí ó gbà jẹ́ ẹẹdẹgbẹsan (1,700) ṣekeli, láìka ohun ọ̀ṣọ́ ati aṣọ olówó iyebíye tí àwọn ọba Midiani wọ̀, ati àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ tí ó wà lọ́rùn àwọn ràkúnmí wọn. Gideoni bá fi wúrà yìí ṣe ère Efodu kan, ó gbé e sí ìlú rẹ̀ ní Ofira, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí bọ ère oriṣa yìí, ó sì di tàkúté fún Gideoni ati ìdílé rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ará Midiani, wọn kò sì lè gbérí mọ́; àwọn ọmọ Israẹli sì sinmi ogun jíjà fún ogoji ọdún, nígbà ayé Gideoni. Gideoni pada sí ilé rẹ̀, ó sì ń gbé ibẹ̀. Aadọrin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí pé ó ní ọpọlọpọ aya. Obinrin rẹ̀ kan tí ń gbè Ṣekemu náà bí ọmọkunrin kan fún un, orúkọ ọmọ yìí ń jẹ́ Abimeleki. Gideoni ọmọ Joaṣi ṣaláìsí lẹ́yìn tí ó ti di arúgbó, wọ́n sin ín sinu ibojì Joaṣi, baba rẹ̀, ní Ofira àwọn ọmọ Abieseri. Bí Gideoni ti ṣaláìsí tán gẹ́rẹ́, àwọn ọmọ Israẹli tún bẹ̀rẹ̀ sí bọ oriṣa Baali, wọ́n sì sọ Baali-beriti di Ọlọrun wọn. Wọn kò ranti OLUWA Ọlọrun wọn tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọ̀tá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Wọn kò ṣe ìdílé Gideoni dáradára bí ó ti tọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀san gbogbo nǹkan dáradára tí òun náà ti ṣe fún Israẹli.

A. Oni 8:18-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Gideoni bi Seba àti Salmunna pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tabori, báwo ni wọ́n ṣe rí?” “Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn. Gideoni dáhùn pé, “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Mo fi OLúWA búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò nípa yín.” Ó yí padà sí Jeteri, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jeteri kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n. Seba àti Salmunna dá Gideoni lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gideoni bọ́ síwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn. Àwọn ará Israẹli wí fún Gideoni pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.” Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jẹ ọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jẹ ọba lórí yín. OLúWA ni yóò jẹ ọba lórí yín.” Gideoni sì wí pé, “Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ó kàn yín láti inú ìkógun.” (Àṣà àwọn ará Iṣmaeli ni láti máa fi yẹtí wúrà sétí.) Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun síbẹ̀. Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó béèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó-lé-ọgọ́rùn-ún méje (1,700) ìwọ̀n ṣékélì, láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ elése àlùkò tí àwọn ọba Midiani ń wọ̀ tàbí àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn. Gideoni fi àwọn wúrà náà ṣe efodu èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Ofira ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ara wọn di àgbèrè nípa sínsìn ní ibẹ̀. Ó sì di ìdẹ̀kùn fún Gideoni àti ìdílé rẹ̀. Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Midiani ba níwájú àwọn ọmọ Israẹli bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbé orí mọ́. Ní ọjọ́ Gideoni, Israẹli wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún. Jerubbaali ọmọ Joaṣi padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀. Àádọ́rin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó. Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣekemu, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Abimeleki. Gideoni ọmọ Joaṣi kú ní ògbólógbòó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ofira ti àwọn ará Abieseri. Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gideoni ni àwọn ará Israẹli ṣe àgbèrè tọ Baali lẹ́yìn, wọ́n fi Baali-Beriti ṣe òrìṣà wọn. Wọn kò sì rántí OLúWA Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn gbogbo tí ó wà ní gbogbo àyíká wọn. Wọ́n kùnà láti fi inú rere hàn sí ìdílé Jerubbaali (èyí ni Gideoni) fún gbogbo oore tí ó ṣe fún wọn.