Gideoni bi Seba àti Salmunna pé, “Irú ọkùnrin tí ẹ pa ní Tabori, báwo ni wọ́n ṣe rí?”
“Àwọn ọkùnrin náà dàbí rẹ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dàbí ọmọ ọba,” ní ìdáhùn wọn.
Gideoni dáhùn pé, “Arákùnrin mi ni wọ́n, àwọn ọmọ ìyá mi. Mo fi OLúWA búra, bí ó bá ṣe pé ẹ dá ẹ̀mí wọn sí, èmi náà ò nípa yín.” Ó yí padà sí Jeteri, ọmọ rẹ̀ tí ó dàgbà jùlọ, ó wí fún un pé, “Pa wọ́n!” Ṣùgbọ́n Jeteri kò fa idà rẹ̀ yọ láti pa wọ́n nítorí ó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé ẹ̀rù sì bà á láti pa wọ́n.
Seba àti Salmunna dá Gideoni lóhùn pé, “Wá pa wá fún raàrẹ, ‘Nítorí bí ènìyàn bá ti rí bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ yóò rí.’ ” Gideoni bọ́ síwájú ó sì pa wọ́n, ó sì mú ohun ọ̀ṣọ́ tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn.
Àwọn ará Israẹli wí fún Gideoni pé, “Jọba lórí wa—ìwọ, àwọn ọmọ rẹ àti àwọn ọmọ ọmọ rẹ pẹ̀lú, nítorí tí ìwọ ti gbà wá lọ́wọ́ àwọn ará Midiani.”
Ṣùgbọ́n Gideoni dá wọn lóhùn pé, “Èmi kì yóò jẹ ọba lórí yín, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ mi kì yóò jẹ ọba lórí yín. OLúWA ni yóò jẹ ọba lórí yín.” Gideoni sì wí pé, “Mo ní ẹ̀bẹ̀ kan tí mo fẹ́ bẹ̀ yín kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín fún mi ní yẹtí kọ̀ọ̀kan láti inú ohun ti ó kàn yín láti inú ìkógun.” (Àṣà àwọn ará Iṣmaeli ni láti máa fi yẹtí wúrà sétí.)
Wọ́n dáhùn pé, “Tayọ̀tayọ̀ ni àwa yóò fi wọ́n sílẹ̀.” Wọ́n tẹ́ aṣọ kan sílẹ̀ ọkùnrin kọ̀ọ̀kan sì ń sọ yẹtí kọ̀ọ̀kan tí ó kàn wọ́n láti ibi ìkógun síbẹ̀. Ìwọ̀n òrùka wúrà tí ó béèrè fún tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀sán, ẹgbẹ̀rún kan ó-lé-ọgọ́rùn-ún méje (1,700) ìwọ̀n ṣékélì, láìka àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti ohun sísorọ̀ tí ó wà lára ìlẹ̀kẹ̀ ọrùn àti aṣọ elése àlùkò tí àwọn ọba Midiani ń wọ̀ tàbí àwọn ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọrùn àwọn ìbákasẹ wọn. Gideoni fi àwọn wúrà náà ṣe efodu èyí tí ó gbé kalẹ̀ ní Ofira ìlú rẹ̀. Àwọn ọmọ Israẹli sì sọ ara wọn di àgbèrè nípa sínsìn ní ibẹ̀. Ó sì di ìdẹ̀kùn fún Gideoni àti ìdílé rẹ̀.
Báyìí ni a ṣe tẹrí àwọn ará Midiani ba níwájú àwọn ọmọ Israẹli bẹ́ẹ̀ ni wọn kò tún gbé orí mọ́. Ní ọjọ́ Gideoni, Israẹli wà ní àlàáfíà fún ogójì ọdún.
Jerubbaali ọmọ Joaṣi padà lọ láti máa gbé ní ìlú rẹ̀. Àádọ́rin ọmọ ni Gideoni bí, nítorí ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìyàwó. Àlè rẹ̀, tó ń gbé ní Ṣekemu, pàápàá bí ọmọkùnrin kan fún un tí ó pe orúkọ rẹ̀ ní Abimeleki. Gideoni ọmọ Joaṣi kú ní ògbólógbòó ọjọ́ rẹ̀, ó sì pọ̀ ní ọjọ́ orí, wọ́n sì sin ín sí ibojì baba rẹ̀ ní Ofira ti àwọn ará Abieseri.
Láìpẹ́ jọjọ lẹ́yìn ikú Gideoni ni àwọn ará Israẹli ṣe àgbèrè tọ Baali lẹ́yìn, wọ́n fi Baali-Beriti ṣe òrìṣà wọn. Wọn kò sì rántí OLúWA Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó gbà wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn gbogbo tí ó wà ní gbogbo àyíká wọn. Wọ́n kùnà láti fi inú rere hàn sí ìdílé Jerubbaali (èyí ni Gideoni) fún gbogbo oore tí ó ṣe fún wọn.