Nigbana li o sọ fun Seba ati Salmunna, wipe, Irú ọkunrin wo li awọn ẹniti ẹnyin pa ni Taboru? Nwọn si dahùn, Bi iwọ ti ri, bẹ̃ni nwọn ri; olukuluku nwọn dabi awọn ọmọ ọba.
On si wipe, Arakunrin mi ni nwọn, ọmọ iya mi ni nwọn iṣe: bi OLUWA ti wà, ibaṣepe ẹnyin da wọn si, emi kì ba ti pa nyin.
On si wi fun Jeteri arẹmọ rẹ̀ pe, Dide, ki o si pa wọn. Ṣugbọn ọmọkunrin na kò fà idà rẹ̀ yọ: nitori ẹ̀ru bà a, nitoripe ọmọde ni iṣe.
Nigbana ni Seba ati Salmunna wipe, Iwọ dide, ki o si kọlù wa: nitoripe bi ọkunrin ti ri, bẹ̃li agbara rẹ̀ ri. Gideoni si dide, o si pa Seba ati Salmunna, o si bọ́ ohun ọṣọ́ wọnni kuro li ọrùn ibakasiẹ wọn.
Nigbana li awọn ọkunrin Israeli wi fun Gideoni pe, Iwọ ma ṣe olori wa, iwọ, ati ọmọ rẹ, ati ọmọ ọmọ rẹ pẹlu: nitoripe o gbà wa lọwọ awọn ara Midiani.
Gideoni si wi fun wọn pe, Emi ki yio ṣe olori nyin, bẹ̃ni ọmọ mi ki yio ṣe olori nyin: OLUWA ni yio ma ṣe alaṣẹ nyin.
Gideoni si wi fun wọn pe, Emi o bère nkan lọwọ nyin, pe ki olukuluku nyin ki o le fi oruka-etí ti mbẹ ninu ikogun rẹ̀ fun mi. (Nitoriti nwọn ní oruka-etí ti wurà, nitoripe ọmọ Iṣmaeli ni nwọn iṣe.)
Nwọn si dahùn wipe, Tinutinu li awa o fi mú wọn wá. Nwọn si tẹ́ aṣọ kan, olukuluku nwọn si sọ oruka-etí ikogun rẹ̀ si i.
Ìwọn oruka-etí wurà na ti o bère lọwọ wọn jẹ́ ẹdẹgbẹsan ṣekeli wurà: làika ohun ọṣọ́ wọnni, ati ohun sisorọ̀, ati aṣọ elesè-àluko ti o wà lara awọn ọba Midiani, ati li àika ẹ̀wọn ti o wà li ọrùn ibakasiẹ wọn.
Gideoni si fi i ṣe ẹ̀wu-efodu kan, o si fi i si ilu rẹ̀, ni Ofra: gbogbo Israeli si ṣe àgbere tọ̀ ọ lẹhin nibẹ̀: o si wa di idẹkun fun Gideoni, ati fun ile rẹ̀.
Bẹ̃li a si tẹ̀ ori Midiani ba niwaju awọn ọmọ Israeli, nwọn kò si gbé ori wọn soke mọ́. Ilẹ na si simi ni ogoji ọdún li ọjọ́ Gideoni.
Jerubbaali ọmọ Joaṣi si lọ o si ngbe ile rẹ̀.
Gideoni si ní ãdọrin ọmọkunrin ti o bi fun ara rẹ̀: nitoripe o lí obinrin pupọ̀.
Ale rẹ̀ ti o wà ni Ṣekemu, on pẹlu bi ọmọkunrin kan fun u, orukọ ẹniti a npè ni Abimeleki.
Gideoni ọmọ Joaṣi si kú li ọjọ́ ogbó, a si sin i si ibojì Joaṣi baba rẹ̀, ni Ofra ti awọn Abieseri.
O si ṣe, lojukanna ti Gideoni kú, li awọn ọmọ Israeli pada, nwọn si ṣe panṣaga tọ̀ Baalimu lọ, nwọn si fi Baaliberiti ṣe oriṣa wọn.
Awọn ọmọ Israeli kò si ranti OLUWA Ọlọrun wọn, ẹniti o gbà wọn lọwọ gbogbo awọn ọtá wọn ni ìha gbogbo:
Bẹ̃ni nwọn kò si ṣe ore fun ile Jerubbaali, ti iṣe Gideoni, gẹgẹ bi gbogbo ire ti o ti ṣe fun Israeli.