Isa 44:21-28
Isa 44:21-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ranti wọnyi, Jakobu ati Israeli; nitori iwọ ni iranṣẹ mi: Emi ti mọ ọ; iranṣẹ mi ni iwọ, Israeli; iwọ ki yio di ẹni-igbagbe lọdọ mi. Mo ti pa irekọja rẹ rẹ́, bi awọsanma ṣiṣú dùdu, ati ẹ̀ṣẹ rẹ, bi kũku: yipada sọdọ mi; nitori mo ti rà ọ pada. Kọrin, ẹnyin ọrun; nitori Oluwa ti ṣe e: kigbe, ẹnyin isalẹ aiye; bú si orin, ẹnyin oke-nla, igbó, ati gbogbo igi inu rẹ̀; nitori Oluwa ti rà Jakobu pada, o si ṣe ara rẹ̀ logo ni Israeli. Bayi ni Oluwa, Olurapada rẹ wi, ati ẹniti o mọ ọ lati inu wá: emi li Oluwa ti o ṣe ohun gbogbo; ti o nikan nà awọn ọrun; ti mo si tikara mi tẹ́ aiye. Ẹniti o sọ àmi awọn eke di asan, ti o si bà awọn alafọṣẹ li ori jẹ, ti o dá awọn ọlọgbọn pada, ti o si sọ imọ̀ wọn di wère. Ti o fi ìdi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ̀ mulẹ, ti o si mu ìmọ awọn ikọ̀ rẹ̀ ṣẹ; ti o wi fun Jerusalemu pe, A o tẹ̀ ọ dó; ati fun gbogbo ilu Juda pe, A o kọ́ nyin, emi o si gbe gbogbo ahoro rẹ̀ dide: Ti o wi fun ibú pe, Gbẹ, emi o si mu gbogbo odò rẹ gbẹ. Ti o wi niti Kirusi pe, Oluṣọ-agutan mi ni, yío si mu gbogbo ifẹ mi ṣẹ: ti o wi niti Jerusalemu pe, A o kọ́ ọ: ati niti tempili pe, A o fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ.
Isa 44:21-28 Yoruba Bible (YCE)
Jakọbu, ranti àwọn nǹkan wọnyi, nítorí pé iranṣẹ mi ni ọ́, ìwọ Israẹli. Èmi ni mo ṣẹ̀dá rẹ, iranṣẹ mi ni ọ́, n kò jẹ́ gbàgbé rẹ, Israẹli. Mo ti ká àìdára rẹ kúrò bí awọsanma, mo ti gbá ẹ̀ṣẹ̀ rẹ dànù bí ìkùukùu. Pada sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ pada. Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLUWA ti ṣe é. Ẹ pariwo, ẹ̀yin ìsàlẹ̀ ilẹ̀. Ẹ kọrin, ẹ̀yin òkè ńlá, ìwọ igbó ati igi inú rẹ̀, nítorí OLUWA ti ra Jakọbu pada, yóo sì ṣe ara rẹ̀ lógo ní Israẹli. Gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà rẹ wí, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ láti inú oyún. Ó ní, “Èmi ni OLUWA, tí mo dá ohun gbogbo. Èmi nìkan ni mo tẹ́ ojú ọ̀run, tí mo sì dá ilẹ̀ ayé tẹ́, èmi tí mo sọ àmì àwọn tí ń woṣẹ́ èké di asán, tí mo sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀. Mo yí ọgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n po mo sì sọ ọgbọ́n wọn di òmùgọ̀. Èmi tí mo jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ iranṣẹ mi, tí mo sì mú ìmọ̀ àwọn ikọ̀ mi ṣẹ, èmi tí mo wí fún Jerusalẹmu pé, ‘Àwọn eniyan yóo máa gbé inú rẹ,’ tí mo sì wí fún àwọn ìlú Juda pé, ‘A óo tún odi yín mọ, n óo sì tún yín kọ́.’ Èmi tí mo pàṣẹ fún agbami òkun pé, ‘Gbẹ! n óo mú kí àwọn odò rẹ gbẹ;’ èmi tí mo sọ fún Kirusi pé: ‘Ìwọ ni ọba tí n óo yàn tí yóo mú gbogbo ìpinnu mi ṣẹ;’ tí mo sọ fún Jerusalẹmu pé: ‘A óo tún odi rẹ̀ mọ,’ tí mo sì sọ fún Tẹmpili pé, ‘A óo tún fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀.’ ”
Isa 44:21-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli. Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe, ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ. Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru, àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀. Padà sọ́dọ̀ mi, nítorí mo ti rà ọ́ padà.” Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLúWA ló ti ṣe èyí; kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀. Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá, ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín, nítorí OLúWA ti ra Jakọbu padà, ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli. “Ohun tí OLúWA wí nìyìí Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́ láti inú ìyá rẹ wá: “Èmi ni OLúWA tí ó ti ṣe ohun gbogbo tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀, ta ni ó ba ààmì àwọn wòlíì èké jẹ́ tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀, tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀ tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀, ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ, “ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘a ó máa gbé inú rẹ̀,’ àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’ àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’ ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ, èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’ ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́; òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,” àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”