“Rántí àwọn nǹkan wọ̀nyí, ìwọ Jakọbu
nítorí ìránṣẹ́ mi ni ìwọ, ìwọ Israẹli.
Èmi ti dá ọ, ìránṣẹ́ mi ni ìwọ ṣe,
ìwọ Israẹli, Èmi kì yóò gbàgbé rẹ.
Èmi ti gbá gbogbo ìkùnà rẹ dànù bí i kurukuru,
àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ bí ìrì òwúrọ̀.
Padà sọ́dọ̀ mi,
nítorí mo ti rà ọ́ padà.”
Kọrin fáyọ̀, ẹ̀yin ọ̀run, nítorí OLúWA ló ti ṣe èyí;
kígbe sókè, ìwọ ilẹ̀ ayé nísàlẹ̀.
Bú sí orin, ẹ̀yin òkè ńlá,
ẹ̀yin igbó àti gbogbo igi yín,
nítorí OLúWA ti ra Jakọbu padà,
ó ti fi ògo rẹ̀ hàn ní Israẹli.
“Ohun tí OLúWA wí nìyìí
Olùràpadà rẹ tí ó mọ ọ́
láti inú ìyá rẹ wá:
“Èmi ni OLúWA
tí ó ti ṣe ohun gbogbo
tí òun nìkan ti na àwọn ọ̀run
tí o sì tẹ́ ayé pẹrẹsẹ òun tìkára rẹ̀,
ta ni ó ba ààmì àwọn wòlíì èké jẹ́
tí ó sì sọ àwọn aláfọ̀ṣẹ di òmùgọ̀,
tí ó dojú ìmọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n délẹ̀
tí ó sì sọ wọ́n di òmùgọ̀,
ẹni tí ó gbé ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jáde
tí ó sì mú àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá sí ìmúṣẹ,
“ẹni tí ó wí nípa ti Jerusalẹmu pé, ‘a ó máa gbé inú rẹ̀,’
àti ní ti àwọn ìlú Juda, ‘A ó tún kọ́,’
àti àwọn ahoro rẹ̀, ‘Èmi yóò mú un bọ̀ sípò,’
ta ni ó sọ fún omi jíjìn pé, ‘Ìwọ gbẹ,
èmi yóò sì mú omi odò rẹ gbẹ,’
ta ni ó sọ nípa Kirusi pé, ‘Òun ni Olùṣọ́-àgùntàn mi
àti pé òun yóò ṣe ohun gbogbo tí mo fẹ́;
òun yóò sọ nípa Jerusalẹmu pé, “Jẹ́ kí a tún kọ́,”
àti nípa tẹmpili, “Jẹ́ kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lé ilẹ̀.” ’ ”