Isa 44:21-28

Isa 44:21-28 YBCV

Ranti wọnyi, Jakobu ati Israeli; nitori iwọ ni iranṣẹ mi: Emi ti mọ ọ; iranṣẹ mi ni iwọ, Israeli; iwọ ki yio di ẹni-igbagbe lọdọ mi. Mo ti pa irekọja rẹ rẹ́, bi awọsanma ṣiṣú dùdu, ati ẹ̀ṣẹ rẹ, bi kũku: yipada sọdọ mi; nitori mo ti rà ọ pada. Kọrin, ẹnyin ọrun; nitori Oluwa ti ṣe e: kigbe, ẹnyin isalẹ aiye; bú si orin, ẹnyin oke-nla, igbó, ati gbogbo igi inu rẹ̀; nitori Oluwa ti rà Jakobu pada, o si ṣe ara rẹ̀ logo ni Israeli. Bayi ni Oluwa, Olurapada rẹ wi, ati ẹniti o mọ ọ lati inu wá: emi li Oluwa ti o ṣe ohun gbogbo; ti o nikan nà awọn ọrun; ti mo si tikara mi tẹ́ aiye. Ẹniti o sọ àmi awọn eke di asan, ti o si bà awọn alafọṣẹ li ori jẹ, ti o dá awọn ọlọgbọn pada, ti o si sọ imọ̀ wọn di wère. Ti o fi ìdi ọ̀rọ iranṣẹ rẹ̀ mulẹ, ti o si mu ìmọ awọn ikọ̀ rẹ̀ ṣẹ; ti o wi fun Jerusalemu pe, A o tẹ̀ ọ dó; ati fun gbogbo ilu Juda pe, A o kọ́ nyin, emi o si gbe gbogbo ahoro rẹ̀ dide: Ti o wi fun ibú pe, Gbẹ, emi o si mu gbogbo odò rẹ gbẹ. Ti o wi niti Kirusi pe, Oluṣọ-agutan mi ni, yío si mu gbogbo ifẹ mi ṣẹ: ti o wi niti Jerusalemu pe, A o kọ́ ọ: ati niti tempili pe, A o fi ipilẹ rẹ̀ sọlẹ.