Isa 43:18-21
Isa 43:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹ máṣe ranti nkan ti iṣaju mọ, ati nkan ti atijọ, ẹ máṣe rò wọn. Kiyesi i, emi o ṣe ohun titun kan; nisisiyi ni yio hù jade; ẹnyin ki yio mọ̀ ọ bi? lõtọ, emi o là ọ̀na kan ninu aginju, ati odò li aṣalẹ̀. Awọn ẹran igbẹ yio yìn mi logo, awọn dragoni ati awọn owiwi; nitori emi o funni li omi li aginjù, ati odo ni aṣalẹ̀, lati fi ohun mimu fun awọn enia mi, ayanfẹ mi; Awọn enia yi ni mo ti mọ fun ara mi; nwọn o fi iyìn mi hàn.
Isa 43:18-21 Yoruba Bible (YCE)
ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́, kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá. Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titun ó ti yọ jáde nisinsinyii, àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀? N óo la ọ̀nà ninu aginjù, n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀. Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo, ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò; nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀, kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu: Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi, kí wọ́n lè kéde ògo mi.
Isa 43:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Gbàgbé àwọn ohun àtẹ̀yìnwá; má ṣe gbé nínú ohun àtijọ́. Wò ó, Èmi ń ṣe ohun tuntun! Nísinsin yìí ó ti yọ sókè; àbí o kò rí i bí? Èmi ń ṣe ọ̀nà kan nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ ṣíṣá. Àwọn ẹhànnà ẹranko bọ̀wọ̀ fún mi, àwọn ajáko àti àwọn òwìwí, nítorí pé mo pèsè omi nínú aṣálẹ̀ àti odò nínú ilẹ̀ sísá, láti fi ohun mímu fún àwọn ènìyàn mi, àyànfẹ́ mi, àwọn ènìyàn tí mo dá fún ara mi kí wọn kí ó lè kéde ìyìn mi.