AISAYA 43

43
OLUWA Ṣe Ìlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là
1Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu,
gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí,
Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ.
Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada;
mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́.
2Nígbà tí o bá ń la ibú omi kọjá,
n óo wà pẹlu rẹ;
nígbà tí o bá la odò ńlá kọjá,
kò ní bò ọ́ mọ́lẹ̀,
nígbà tí o bá ń kọjá ninu iná, kò ní jó ọ.
Ahọ́n iná kò ní jó ọ run.
3Nítorí èmi ni OLUWA Ọlọrun rẹ,
Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùgbàlà rẹ.
Mo fi Ijipti, lélẹ̀, láti rà ọ́ pada,
mo sì fi Etiopia ati Seba lélẹ̀ mo ti fi ṣe pàṣípààrọ̀ rẹ.
4Nítorí pé o ṣọ̀wọ́n lójú mi, o níyì, mo sì fẹ́ràn rẹ,
mo fi àwọn eniyan rọ́pò rẹ;
mo sì fi ẹ̀mí àwọn orílẹ̀-èdè dípò ẹ̀mí rẹ.
5Má bẹ̀rù nítorí mo wà pẹlu rẹ,
n óo kó àwọn ọmọ rẹ wá láti ìlà oòrùn,
n óo sì ko yín jọ láti ìwọ̀ oòrùn.
6N óo pàṣẹ fún ìhà àríwá pé,
‘Dá wọn sílẹ̀.’
N óo sọ fún ìhà gúsù pé,
‘O kò gbọdọ̀ dá wọn dúró.’
Kó àwọn ọmọ mi ọkunrin wá láti òkèèrè,
sì kó àwọn ọmọ mi obinrin wá láti òpin ayé,
7gbogbo àwọn tí à ń fi orúkọ mi pè,
àwọn tí mo dá fún ògo mi,
àwọn tí mo fi ọwọ́ mi ṣẹ̀dá wọn.”
Ẹlẹ́rìí OLUWA ni Israẹli
8Ẹ mú àwọn eniyan mi jáde,
àwọn tí wọ́n ní ojú, ṣugbọn tí ojú wọn ti fọ́,
wọ́n ní etí, ṣugbọn etí wọn ti di.
9Jẹ́ kí gbogbo orílẹ̀-èdè péjọ,
kí àwọn eniyan àgbáyé parapọ̀.
Èwo ninu wọn ni ó lè kéde irú àsọtẹ́lẹ̀ yìí,
tí ó lè fi àwọn ohun àtijọ́ hàn wá;
kí wọn pe ẹlẹ́rìí wọn wá, kí á lè mọ̀ pé ẹjọ́ wọn tọ́,
kí àwọn ẹlòmíràn lè gbọ́, kì wọn sì jẹ́rìí pé, “Òtítọ́ ni.”
10OLUWA ní, “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí mi,
ẹ̀yin ni iranṣẹ mi tí mo yàn;
kí ẹ lè mọ̀ mí, kí ẹ sì gbà mí gbọ́,
kí ó sì ye yín pé, Èmi ni.
A kò dá Ọlọrun kankan ṣáájú mi,
òmíràn kò sì ní wáyé lẹ́yìn mi.
11“Èmi ni OLUWA,
kò sí olùgbàlà kan, yàtọ̀ sí mi.
12Mo ti sọ̀rọ̀ ìṣípayá, mo ti gba eniyan là,
mo sì ti kéde,
nígbà tí kò sí Ọlọrun àjèjì láàrin yín;
ẹ̀yin sì ni ẹlẹ́rìí mi.
Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.
13Èmi ni Ọlọrun,
láti ìsinsìnyìí lọ, Èmi ni.
Kò sí ẹnìkan tí ó lè gba eniyan kalẹ̀ lọ́wọ́ mi:
Ta ni le dínà ohun tí mo bá níí ṣe?”
Sísá kúrò ní Babiloni
14OLUWA, Ẹni Mímọ́ Israẹli, Olùràpadà yín, ní,
“N óo ranṣẹ sí Babiloni nítorí yín,
n óo dá gbogbo ọ̀pá ìlẹ̀kùn ibodè,
ariwo ẹ̀rín àwọn ará Kalidea yóo sì di ẹkún.
15Èmi ni OLUWA, Ẹni Mímọ́ yín,
Ẹlẹ́dàá Israẹli, Ọba yín.”
16OLUWA tí ó la ọ̀nà sí ojú òkun,
tí ó la ọ̀nà lórí agbami ńlá;
17ẹni tí ó kó kẹ̀kẹ́ ogun ati ẹṣin jáde, ogun, ati àwọn ọmọ-ogun;
wọ́n dùbúlẹ̀ wọn kò lè dìde mọ́,
wọ́n kú bí iná fìtílà.
18ÓLUWA ní, “Ẹ gbàgbé àwọn ohun àtijọ́,
kí ẹ sì mú ọkàn kúrò ninu ohun tí ó ti kọjá.
19Ẹ wò ó! Mò ń ṣe nǹkan titun
ó ti yọ jáde nisinsinyii,
àbí ẹ kò ṣe akiyesi rẹ̀?
N óo la ọ̀nà ninu aginjù,
n óo sì mú kí omi máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.
20Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo,
ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò;
nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀,
kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu:
21Àwọn tí mo fọwọ́ mi dá fún ara mi,
kí wọ́n lè kéde ògo mi.
Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli
22“Sibẹsibẹ, ẹ kò ké pè mí, ẹ̀yin ọmọ Jakọbu,
ọ̀rọ̀ mi ti su yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
23Ẹ kò wá fi aguntan rúbọ sí mi,
tabi kí ẹ wá fi ẹbọ rírú bu ọlá fún mi.
N kò fi tipátipá mu yín rúbọ,
bẹ́ẹ̀ ni n kò sọ pé dandan ni kí ẹ mú turari wá.
24Ẹ kò fowó yín ra turari olóòórùn dídùn fún mi,
tabi kí ẹ fi ọ̀rá ẹbọ yín tẹ́ mi lọ́rùn.
Kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ yín yọ mí lẹ́nu,
ẹ sì ń dààmú mi pẹlu àìdára yín.
25Èmi, èmi ni mo pa ẹ̀ṣẹ̀ yín rẹ́,
nítorí ti ara mi;
n kò sì ní ranti àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín mọ́.
26“Ẹ rán mi létí ọ̀rọ̀ yín kí á jọ ṣàríyànjiyàn;
ẹ ro ẹjọ́ tiyín,
kí á lè da yín láre.
27Baba ńlá yín àkọ́kọ́ ṣẹ̀,
àwọn aṣiwaju yín náà sì ṣẹ̀ mí.
28Nítorí náà mo sọ àwọn olórí ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,
mo fi Jakọbu sílẹ̀ fún ìparun;
mo sì sọ Israẹli di ẹni ẹ̀sín.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 43: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa