Isa 43

43
OLUWA Ṣe Ìlérí láti Gba Àwọn Eniyan Rẹ̀ Là
1ṢUGBỌN nisisiyi bayi ni Oluwa wi, ẹniti o dá ọ, Jakobu, ati ẹniti o mọ ọ, Israeli, Má bẹru: nitori mo ti rà ọ pada, mo ti pè ọ li orukọ rẹ, ti emi ni iwọ.
2Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ: nigbati iwọ ba nrìn ninu iná, ki yio jo ọ, bẹ̃ni ọwọ́-iná ki yio ràn ọ.
3Nitori emi li Oluwa Ọlọrun rẹ, Ẹni-Mimọ Israeli, Olugbala rẹ: mo fi Egipti ṣe irapada rẹ, mo si fi Etiopia ati Seba fun ọ.
4Niwọn bi iwọ ti ṣe iyebiye to loju mi, ti iwọ ṣe ọlọla, emi si ti fẹ ọ: nitorina emi o fi enia rọpò rẹ, ati enia dipo ẹmi rẹ.
5Má bẹ̀ru: nitori emi wà pẹlu rẹ; emi o mu iru-ọmọ rẹ lati ìla-õrun wá, emi o si ṣà ọ jọ lati ìwọ-õrun wá.
6Emi o wi fun ariwa pe, Da silẹ; ati fun gusu pe, Máṣe da duro; mu awọn ọmọ mi ọkunrin lati okere wá, ati awọn ọmọ mi obinrin lati opin ilẹ wá.
7Olukuluku ẹniti a npè li orukọ mi: nitori mo ti dá a fun ogo mi, mo ti mọ ọ, ani, mo ti ṣe e pé.
Ẹlẹ́rìí OLUWA ni Israẹli
8Mu awọn afọju enia ti o li oju jade wá, ati awọn aditi ti o li eti.
9Jẹ ki gbogbo awọn orilẹ-ède ṣa ara wọn jọ pọ̀, ki awọn enia pejọ; tani ninu wọn ti o le sọ eyi, ti o si le fi ohun atijọ han ni? jẹ ki wọn mu awọn ẹlẹri wọn jade, ki a le dá wọn lare; nwọn o si gbọ́, nwọn o si wipe, Õtọ ni.
10Ẹnyin li ẹlẹri mi, ni Oluwa wi, ati iranṣẹ mi ti mo ti yàn: ki ẹnyin ki o le mọ̀, ki ẹ si gbà mi gbọ́ ki o si ye nyin pe, Emi ni; a kò mọ̀ Ọlọrun kan ṣãju mi, bẹ̃ni ọkan kì yio si hù lẹhin mi.
11Emi, ani emi ni Oluwa; ati lẹhin mi, kò si olugbala kan.
12Emi ti sọ, mo ti gbalà, mo si ti fi hàn, nigbati ko si ajeji ọlọrun kan lãrin nyin: ẹnyin ni iṣe ẹlẹri mi, li Oluwa wi, pe, Emi li Ọlọrun.
13Lõtọ, ki ọjọ ki o to wà, Emi na ni, ko si si ẹniti o le gbani kuro li ọwọ́ mi: emi o ṣiṣẹ, tani o le yi i pada?
Sísá kúrò ní Babiloni
14Bayi li Oluwa, olurapada nyin, Ẹni-Mimọ Israeli wi; Nitori nyin ni mo ṣe ranṣẹ si Babiloni, ti mo si jù gbogbo wọn bi isansa, ati awọn ara Kaldea, sisalẹ si awọn ọkọ̀ igbe-ayọ̀ wọn.
15Emi ni Oluwa, Ẹni-Mimọ́ nyin, ẹlẹda Israeli Ọba nyin.
16Bayi li Oluwa wi, ẹniti o la ọ̀na ninu okun, ati ipa-ọ̀na ninu alagbara omi;
17Ẹniti o mu kẹkẹ ati ẹṣin jade, ogun ati agbara; nwọn o jumọ dubulẹ, nwọn kì yio dide: nwọn run, a pa wọn bi owú fitila.
18Ẹ máṣe ranti nkan ti iṣaju mọ, ati nkan ti atijọ, ẹ máṣe rò wọn.
19Kiyesi i, emi o ṣe ohun titun kan; nisisiyi ni yio hù jade; ẹnyin ki yio mọ̀ ọ bi? lõtọ, emi o là ọ̀na kan ninu aginju, ati odò li aṣalẹ̀.
20Awọn ẹran igbẹ yio yìn mi logo, awọn dragoni ati awọn owiwi; nitori emi o funni li omi li aginjù, ati odo ni aṣalẹ̀, lati fi ohun mimu fun awọn enia mi, ayanfẹ mi;
21Awọn enia yi ni mo ti mọ fun ara mi; nwọn o fi iyìn mi hàn.
Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli
22Ṣugbọn iwọ kò ké pe mi, Jakobu; ṣugbọn ãrẹ̀ mu ọ nitori mi, iwọ Israeli.
23Iwọ ko mu ọmọ-ẹran ẹbọ sisun rẹ fun mi wá; bẹ̃ni iwọ ko fi ẹbọ rẹ bu ọlá fun mi. Emi ko fi ọrẹ mu ọ sìn, emi ko si fi turari da ọ li agara.
24Iwọ ko fi owo rà kalamu olõrun didun fun mi, bẹ̃ni iwọ ko fi ọra ẹbọ rẹ yó mi; ṣugbọn iwọ fi ẹ̀ṣẹ rẹ mu mi ṣe lãla, iwọ si fi aiṣedẽde rẹ da mi li agara.
25Emi, ani emi li ẹniti o pa irekọja rẹ rẹ́ nitori ti emi tikalami, emi ki yio si ranti ẹ̀ṣẹ rẹ.
26Rán mi leti: ki a jumọ sọ ọ; iwọ rò, ki a le da ọ lare.
27Baba rẹ iṣãju ti ṣẹ̀, awọn olukọni rẹ ti yapa kuro lọdọ mi.
28Nitorina mo ti sọ awọn olori ibi mimọ́ na di aimọ́, mo si ti fi Jakobu fun egún, ati Israeli fun ẹ̀gan.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 43: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa