Isa 40:1-17

Isa 40:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ẹ tù enia mi ninu, ẹ tù wọn ninu, ni Ọlọrun nyin wi. Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo. Ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ́ ni aginjù fun Ọlọrun wa. Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òke-nla ati òke kékèké ni a o si rẹ̀ silẹ: wiwọ́ ni a o si ṣe ni titọ́, ati ọ̀na pàlapala ni a o sọ di titẹ́ju: A o si fi ogo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu Oluwa li o sọ ọ. Ohùn na wipe, Kigbe. On si wipe, Igbe kini emi o ke? Gbogbo ẹran-ara ni koriko, gbogbo ogo rẹ̀ si dabi ìtànná igbẹ́: Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia. Koriko nrọ, ìtànná nrẹ̀: ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun wa yio duro lailai. Iwọ onihinrere Sioni, gùn òke giga lọ: Iwọ onihin-rere Jerusalemu, gbé ohùn rẹ soke pẹlu agbara; gbé e soke, má bẹ̀ru; wi fun awọn ilu Juda pe, Ẹ wò Ọlọrun nyin! Kiyesi i, Oluwa Jehofah yio wá ninu agbara, apá rẹ̀ yio ṣe akoso fun u: kiyesi i, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ si mbẹ niwaju rẹ̀. On o bọ́ ọwọ-ẹran rẹ̀ bi oluṣọ-agùtan: yio si fi apá rẹ̀ ko awọn ọdọ-agùtan, yio si kó wọn si aiya rẹ̀, yio si rọra dà awọn ti o loyun. Tali o ti wọ̀n omi ni kòto-ọwọ́ rẹ̀, ti o si ti fi ika wọ̀n ọrun, ti o si ti kó erùpẹ aiye jọ sinu òṣuwọn, ti o si fi ìwọn wọ̀n awọn oke-nla, ati awọn oke kékèké ninu òṣuwọn? Tali o ti tọ́ Ẹmi Oluwa, tabi ti iṣe igbimọ̀ rẹ̀ ti o kọ́ ọ? Tali o mba a gbìmọ, tali o si kọ́ ọ lẹkọ́, ti o si kọ́ ọ ni ọ̀na idajọ, ti o si kọ́ ọ ni ìmọ, ti o si fi ọ̀na oye hàn a? Kiyesi i, awọn orilẹ-ède dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si kà wọn bi ekúru kiun ninu ìwọn: kiyesi i, o nmu awọn erekùṣu bi ohun diẹ kiun. Lebanoni kò si tó fi joná, bẹ̃ni awọn ẹranko ibẹ kò to lati fi rubọ sisun. Gbogbo orilẹ-ède li o dabi ofo niwaju rẹ̀; a si kà wọn si fun u bi ohun ti o rẹ̀hin jù ofo ati asan lọ.

Isa 40:1-17 Yoruba Bible (YCE)

Ọlọrun yín ní, “Ẹ tù wọ́n ninu, ẹ tu àwọn eniyan mi ninu. Ẹ bá Jerusalẹmu sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ ẹ ké sí i pé, ogun jíjà rẹ̀ ti parí, a ti dárí àìṣedéédé rẹ̀ jì í. OLUWA ti jẹ ẹ́ níyà ní ìlọ́po meji nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.” Ẹ gbọ́ ohùn akéde kan tí ń wí pé, “Ẹ tún ọ̀nà OLUWA ṣe ninu aginjù, ẹ la òpópónà títọ́ fún Ọlọrun wa ninu aṣálẹ̀. Gbogbo àfonífojì ni a óo ru sókè, a óo sì sọ àwọn òkè ńlá ati òkè kéékèèké di pẹ̀tẹ́lẹ̀: Gbogbo ọ̀nà tí ó wọ́ ni yóo di títọ́, ọ̀nà gbágun-gbàgun yóo sì di títẹ́jú. Ògo OLUWA yóo farahàn, gbogbo eniyan yóo sì jọ fojú rí i. OLUWA ni ó fi ẹnu ara rẹ̀ sọ bẹ́ẹ̀.” Mo gbọ́ ohùn kan tí ń wí pé, “Kígbe!” Mo bá bèèrè pé, “Igbe kí ni kí n ké?” Ó ní, “Kígbe pé, koríko ṣá ni gbogbo eniyan, gbogbo ẹwà sì dàbí òdòdó inú pápá. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀ nígbà tí OLUWA bá fẹ́ afẹ́fẹ́ lù ú. Dájúdájú koríko ni eniyan. Koríko a máa rọ, òdòdó a sì máa rẹ̀; ṣugbọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun wa dúró títí lae.” Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni, kí o máa kéde ìyìn rere. Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu, ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rere ké sókè má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú Juda pé, “Ẹ wo Ọlọrun yín.” Ẹ wò ó! OLUWA Ọlọrun ń bọ̀ pẹlu agbára ipá rẹ̀ ni yóo fi máa ṣe àkóso. Ẹ wò ó! Èrè rẹ̀ ń bẹ lọ́wọ́ rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ sì ń bẹ níwájú rẹ̀. Yóo bọ́ agbo ẹran bí olùṣọ́-aguntan. Yóo kó àwọn ọ̀dọ́ aguntan jọ sí apá rẹ̀, yóo gbé wọn mọ́ àyà rẹ̀. Yóo sì máa fi sùúrù da àwọn tí wọn lọ́mọ lẹ́yìn láàrin wọn. Ta ló lè fi kòtò ọwọ́ wọn omi òkun? Ta ló lè fìka wọn ojú ọ̀run, Kí ó kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé sinu òṣùnwọ̀n? Ta ló lè gbé àwọn òkè ńlá ati àwọn kéékèèké sórí ìwọ̀n? Ta ló darí Ẹ̀mí OLUWA, ta ló sì tọ́ ọ sọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? Ọwọ́ ta ni OLUWA ti gba ìmọ̀ràn tí ó fi ní òye, ta ló kọ́ ọ bí wọ́n ṣe ń dájọ́ ẹ̀tọ́, tí ó kọ́ ọ ní ìmọ̀, tí ó sì fi ọ̀nà òye hàn án? Wò ó, àwọn orílẹ̀-èdè dàbí ìkán omi kan ninu garawa omi, ati bí ẹyọ eruku kan lórí òṣùnwọ̀n. Ẹ wò ó, ó mú àwọn erékùṣù lọ́wọ́ bí àtíkè. Gbogbo igi igbó Lẹbanoni kò tó fún iná ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹranko ibẹ̀ kò tó fún ẹbọ sísun. Gbogbo orílẹ̀-èdè kò tó nǹkan níwájú rẹ̀, wọn kò jámọ́ nǹkan lójú rẹ̀, òfo ni wọ́n.

Isa 40:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ẹ tù ú nínú, ẹ tu ènìyàn mi nínú, ni Ọlọ́run yín wí. Sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fún Jerusalẹmu kí o sì kéde fún un pé iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ ti parí, pé à ti san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, pé ó ti rí i gbà láti ọwọ́ OLúWA ìlọ́po méjì fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀. Ohùn ẹni tí ń kígbe ní ijù: “Ẹ tún ọ̀nà OLúWA ṣe, ṣe òpópó tí ó tọ́ ní aginjù fún Ọlọ́run wa. Gbogbo Àfonífojì ni a ó gbé sókè, gbogbo òkè ńlá àti òkè kékeré ni yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀; wíwọ́ ni a ó sọ di títọ́ àti ọ̀nà pálapàla ni a óò sọ di títẹ́jú pẹrẹsẹ, Ògo OLúWA yóò sì di mí mọ̀ gbogbo ènìyàn lápapọ̀ ni yóò sì rí i. Nítorí ẹnu OLúWA ni ó ti sọ ọ́.” Ohùn kan wí pé, “Kígbe sókè.” Èmi sì sọ pé, “Igbe kí ni èmi ó ké?” “Gbogbo ènìyàn dàbí i koríko, àti gbogbo ògo wọn dàbí ìtànná igbó. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, nítorí èémí OLúWA ń fẹ́ lù wọ́n. Nítòótọ́ koríko ni àwọn ènìyàn. Koríko ń rọ ìtànná sì ń rẹ̀, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa dúró títí láé.” Ìwọ tí o mú ìyìn ayọ̀ wá sí Sioni, lọ sí orí òkè gíga. Ìwọ tí ó mú ìyìn ayọ̀ wá sí Jerusalẹmu, gbé ohùn rẹ sókè pẹ̀lú ariwo, gbé e sókè, má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú u Juda, “Ọlọ́run rẹ nìyìí!” Wò ó, OLúWA Olódùmarè náà ń bọ̀ wá pẹ̀lú agbára, apá rẹ̀ sì ń jẹ ọba fún un. Wò ó, èrè rẹ̀ sì wà pẹ̀lú rẹ̀, àti ìdápadà rẹ̀ tí ń bá a bọ̀ wá. Ó ń tọ́ àwọn agbo rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́-àgùntàn: Ó kó àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ní apá rẹ̀. Ó sì gbé wọn súnmọ́ oókan àyà rẹ̀; ó sì fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ darí àwọn tí ó ní. Ta ni ó tiwọn omi nínú kòtò ọwọ́ rẹ̀, tàbí pẹ̀lú ìbú ọwọ́ rẹ̀ tí ó wọn àwọn ọ̀run? Ta ni ó ti kó erùpẹ̀ ilẹ̀ ayé jọ nínú apẹ̀rẹ̀, tàbí kí ó wọn àwọn òkè ńlá lórí ìwọ̀n àti òkè kéékèèkéé nínú òṣùwọ̀n? Ta ni ó ti mọ ọkàn OLúWA, tàbí tí ó ti tọ́ ọ ṣọ́nà gẹ́gẹ́ bí olùdámọ̀ràn rẹ̀? Ta ni OLúWA ké sí kí ó là á lọ́yẹ àti ta ni ó kọ́ òun ní ọ̀nà tí ó tọ́? Ta ni ẹni náà tí ó kọ́ ọ ní ọgbọ́n tàbí tí ó fi ipa ọ̀nà òye hàn án? Nítòótọ́ àwọn orílẹ̀-èdè dàbí i ẹ̀kún omi nínú garawa; a kà wọ́n sí gẹ́gẹ́ bí eruku lórí ìwọ̀n; ó wọn àwọn erékùṣù àfi bí eruku múnúmúnú ni wọ́n. Lebanoni kò tó fún pẹpẹ iná, tàbí kí àwọn ẹranko rẹ̀ kí ó tó fún ẹbọ sísun. Níwájú rẹ̀ ni gbogbo orílẹ̀-èdè dàbí ohun tí kò sí; gbogbo wọn ló kà sí ohun tí kò wúlò tí kò tó ohun tí kò sí.

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa