Ẹ tù enia mi ninu, ẹ tù wọn ninu, ni Ọlọrun nyin wi.
Ẹ sọ ọ̀rọ ìtunu fun Jerusalemu, ki ẹ si ké si i pe, ogun jijà rẹ tán, pe, a dari aiṣedẽde rẹ jì: nitoripe o ti gbà nigba meji lati ọwọ́ Oluwa wá fun ẹ̀ṣẹ rẹ̀ gbogbo.
Ohùn ẹniti nkigbe ni ijù, ẹ tún ọ̀na Oluwa ṣe, ṣe opópo titọ́ ni aginjù fun Ọlọrun wa.
Gbogbo afonifoji ni a o gbe soke, gbogbo òke-nla ati òke kékèké ni a o si rẹ̀ silẹ: wiwọ́ ni a o si ṣe ni titọ́, ati ọ̀na pàlapala ni a o sọ di titẹ́ju:
A o si fi ogo Oluwa hàn, gbogbo ẹran-ara ni yio jùmọ ri i: nitori ẹnu Oluwa li o sọ ọ.
Ohùn na wipe, Kigbe. On si wipe, Igbe kini emi o ke? Gbogbo ẹran-ara ni koriko, gbogbo ogo rẹ̀ si dabi ìtànná igbẹ́:
Koriko nrọ, ìtànná eweko nrẹ̀: nitoripe ẹmi Oluwa ti fẹ́ lù u: dajudaju koriko ni enia.
Koriko nrọ, ìtànná nrẹ̀: ṣugbọn ọ̀rọ Ọlọrun wa yio duro lailai.
Iwọ onihinrere Sioni, gùn òke giga lọ: Iwọ onihin-rere Jerusalemu, gbé ohùn rẹ soke pẹlu agbara; gbé e soke, má bẹ̀ru; wi fun awọn ilu Juda pe, Ẹ wò Ọlọrun nyin!
Kiyesi i, Oluwa Jehofah yio wá ninu agbara, apá rẹ̀ yio ṣe akoso fun u: kiyesi i, ère rẹ̀ wà pẹlu rẹ̀, ẹ̀san rẹ̀ si mbẹ niwaju rẹ̀.
On o bọ́ ọwọ-ẹran rẹ̀ bi oluṣọ-agùtan: yio si fi apá rẹ̀ ko awọn ọdọ-agùtan, yio si kó wọn si aiya rẹ̀, yio si rọra dà awọn ti o loyun.
Tali o ti wọ̀n omi ni kòto-ọwọ́ rẹ̀, ti o si ti fi ika wọ̀n ọrun, ti o si ti kó erùpẹ aiye jọ sinu òṣuwọn, ti o si fi ìwọn wọ̀n awọn oke-nla, ati awọn oke kékèké ninu òṣuwọn?
Tali o ti tọ́ Ẹmi Oluwa, tabi ti iṣe igbimọ̀ rẹ̀ ti o kọ́ ọ?
Tali o mba a gbìmọ, tali o si kọ́ ọ lẹkọ́, ti o si kọ́ ọ ni ọ̀na idajọ, ti o si kọ́ ọ ni ìmọ, ti o si fi ọ̀na oye hàn a?
Kiyesi i, awọn orilẹ-ède dabi iró kan ninu omi ladugbo, a si kà wọn bi ekúru kiun ninu ìwọn: kiyesi i, o nmu awọn erekùṣu bi ohun diẹ kiun.
Lebanoni kò si tó fi joná, bẹ̃ni awọn ẹranko ibẹ kò to lati fi rubọ sisun.
Gbogbo orilẹ-ède li o dabi ofo niwaju rẹ̀; a si kà wọn si fun u bi ohun ti o rẹ̀hin jù ofo ati asan lọ.