Isa 34:1-8

Isa 34:1-8 Yoruba Bible (YCE)

Ẹ súnmọ́ ibí, kí ẹ wá gbọ́, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè, ẹ tẹ́tí sílẹ̀, gbogbo ẹ̀yin eniyan. Kí ilẹ̀ gbọ́ ati gbogbo ohun tí ó wà lórí rẹ̀, kí ayé tẹ́tí sílẹ̀ pẹlu gbogbo nǹkan tí ń ti inú rẹ̀ jáde. Nítorí OLUWA ń bínú sí gbogbo orílẹ̀-èdè, inú rẹ̀ sì ń ru sí àwọn eniyan ibẹ̀. Ó ti fi wọ́n sílẹ̀ fún ìparun, ó sì ti fà wọ́n kalẹ̀ fún pípa. A óo wọ́ òkú wọn jùnù, òkú wọn yóo máa rùn; ẹ̀jẹ̀ wọn yóo sì máa ṣàn lórí àwọn òkè. Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo gbọ̀n dànù a óo ká awọsanma bí ẹni ká ìwé. Oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ bí ewé tií rẹ̀ sílẹ̀ lára ìtàkùn àjàrà, àní, bí ewé tií wọ́ dànù lórí igi ọ̀pọ̀tọ́. Nítorí mo ti rẹkẹ idà mi lókè ọ̀run, yóo sọ̀kalẹ̀ láti ṣe ìdájọ́ àwọn ará Edomu; yóo sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn tí mo fẹ́ parun. OLUWA ní idà kan tí a tì bọ inú ẹ̀jẹ̀, a rì í sinu ọ̀rá, pẹlu ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ aguntan ati ti ewúrẹ́, ati ọ̀rá ara kíndìnrín àgbò. Nítorí pé OLUWA yóo rú ẹbọ ní Bosira, yóo sì pa ọpọlọpọ eniyan ní ilẹ̀ Edomu. Àwọn mààlúù igbó yóo kú pẹlu wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ati àwọn akọ mààlúù ńlá. Ilẹ̀ wọn yóo kún fún ẹ̀jẹ̀, ọ̀rá eniyan yóo sì mú kí ilẹ̀ wọn lẹ́tù lójú. Nítorí OLUWA ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀ fún ẹ̀san, ó ti ya ọdún kan sọ́tọ̀ tí yóo gbèjà Sioni.

Isa 34:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Súnmọ́ tòsí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́, tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn jẹ́ kí ayé gbọ́, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú rẹ̀ jáde. Nítorí ìbínú OLúWA ń bẹ lára gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ìrunú rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn: o ti fi wọ́n fún pípa, Àwọn ti a pa nínú wọn ni a ó sì jù sóde, òórùn wọn yóò ti inú òkú wọn jáde, àwọn òkè ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́, a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i tákàdá, gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀, bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà, àti bí i bíbọ́ èso lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu, sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́. Idà OLúWA kún fún ẹ̀jẹ̀ a mú un sanra fún ọ̀rá, àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́, fún ọ̀rá ìwé àgbò— nítorí OLúWA ni ìrúbọ kan ní Bosra, àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Edomu. Àti àwọn àgbáǹréré yóò ba wọn sọ̀kalẹ̀ wá, àti àwọn ẹgbọrọ màlúù pẹ̀lú àwọn akọ màlúù, ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin, a ó sì fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ràá. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san OLúWA ni, àti ọdún ìsanpadà, nítorí ọ̀ràn Sioni.