Isaiah 34:1-8

Isaiah 34:1-8 YCB

Súnmọ́ tòsí, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè láti gbọ́, tẹ́tí sílẹ̀ ẹ̀yin ènìyàn jẹ́ kí ayé gbọ́, àti ẹ̀kún rẹ̀, ayé àti ohun gbogbo tí ó ti inú rẹ̀ jáde. Nítorí ìbínú OLúWA ń bẹ lára gbogbo orílẹ̀-èdè, àti ìrunú rẹ̀ lórí gbogbo ogun wọn: o ti fi wọ́n fún pípa, Àwọn ti a pa nínú wọn ni a ó sì jù sóde, òórùn wọn yóò ti inú òkú wọn jáde, àwọn òkè ńlá yóò sì yọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ wọn Gbogbo àwọn ogun ọ̀run ni yóò di yíyọ́, a ó sì ká àwọn ọ̀run jọ bí i tákàdá, gbogbo ogun wọn yóò si ṣubú lulẹ̀, bí ewé ti n bọ́ kúrò lára àjàrà, àti bí i bíbọ́ èso lára igi ọ̀pọ̀tọ́. Nítorí ti a rẹ idà mi ní ọ̀run, kíyèsi í, yóò sọ̀kalẹ̀ wá sórí Edomu, sórí àwọn ènìyàn tí mo ti parun fún ìdájọ́. Idà OLúWA kún fún ẹ̀jẹ̀ a mú un sanra fún ọ̀rá, àti fún ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́-àgùntàn àti ewúrẹ́, fún ọ̀rá ìwé àgbò— nítorí OLúWA ni ìrúbọ kan ní Bosra, àti ìpakúpa ńlá kan ní ilẹ̀ Edomu. Àti àwọn àgbáǹréré yóò ba wọn sọ̀kalẹ̀ wá, àti àwọn ẹgbọrọ màlúù pẹ̀lú àwọn akọ màlúù, ilé wọn ni a ó fi ẹ̀jẹ̀ rin, a ó sì fi ọ̀rá sọ ekuru wọn di ọlọ́ràá. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san OLúWA ni, àti ọdún ìsanpadà, nítorí ọ̀ràn Sioni.