Isa 33:18-21
Isa 33:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Aiyà rẹ yio ṣe aṣaro ẹ̀ru nla. Nibo ni akọwe wà? nibo ni ẹniti nwọ̀n nkan gbe wà? nibo ni ẹniti o nkà ile-ẹ̀ṣọ wọnni gbe wà? Iwọ kì yio ri awọn enia ti o muná; awọn enia ti ọ̀rọ wọn jinlẹ jù eyiti iwọ le gbọ́, ti ahọn wọn ṣe ololò, ti kò le ye ọ. Wo Sioni, ilu ajọ afiyesi wa: oju rẹ yio ri Jerusalemu ibugbe idakẹjẹ, agọ́ ti a kì yio tú palẹ mọ; kò si ọkan ninu ẽkàn rẹ ti a o ṣí ni ipò lai, bẹ̃ni kì yio si ọkan ninu okùn rẹ̀ ti yio já. Ṣugbọn nibẹ ni Oluwa ogo yio ri fun wa, bi ibi odò gbigbòro on odò ṣiṣàn; nibiti ọkọ̀ alajẹ̀ kì yio kọja, bẹ̃ni ọkọ̀ nlanla ki yio là a ja.
Isa 33:18-21 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ óo máa ronú ìnira tí ẹ ti ní pé: “Níbo ni akọ̀wé wà? Níbo ni ẹni tí ń gba owó orí wà? Níbo sì ni ẹni tí ń ka ilé ìṣọ́ wà?” Ẹ kò ní rí àwọn aláfojúdi náà mọ́, àwọn tí wọn ń fọ èdè tí kò ní ìtumọ̀ si yín, tí wọn ń kólòlò ní èdè tí ẹ kò gbọ́. Ẹ wo Sioni, ìlú tí a yà sọ́tọ̀ fún àjọ̀dún. Ẹ óo fi ojú rí Jerusalẹmu, ibùgbé alaafia, tí àgọ́ rẹ̀ kò ní ṣídìí, tí èèkàn tí a fi kàn án mọ́lẹ̀ kò ní hú laelae, bẹ́ẹ̀ ni okùn tí a fi so ó mọ́lẹ̀ kò ní já. Ṣugbọn níbẹ̀ ni OLUWA, ninu ògo rẹ̀, yóo jẹ́ odò ńlá ati odò tí ń ṣàn fún wa; níbi tí ọkọ̀ ọlọ́pọ́n kò lè dé, ọkọ̀ ojú omi kò sì ní lè kọjá níbẹ̀.
Isa 33:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá: “Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà? Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà? Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?” Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́, àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin, pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni. Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa, ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu, ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà; àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já. Níbẹ̀ ni OLúWA yóò ti jẹ́ Alágbára kan fún wa. Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńláńlá àti odò kéékèèkéé. Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn, ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.