Isa 31:1
Isa 31:1 Bibeli Mimọ (YBCV)
EGBE ni fun awọn ti o sọkalẹ lọ si Egipti fun iranlọwọ; ti nwọn gbẹkẹlẹ ẹṣin, ti nwọn gbiyèle kẹkẹ́, nitoriti nwọn pọ̀: nwọn si gbẹkẹle ẹlẹṣin nitoriti nwọn li agbara jọjọ; ṣugbọn ti nwọn kò wò Ẹni-Mimọ Israeli, nwọn kò si wá Oluwa!
Pín
Kà Isa 31Isa 31:1 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn tí ó ń lọ sí Ijipti fún ìrànlọ́wọ́ gbé! Àwọn tí wọ́n gbójú lé ẹṣin; tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé kẹ̀kẹ́ ogun nítorí pé wọ́n pọ̀, tí wọ́n gbójú lé ẹṣin nítorí pé wọ́n lágbára! Wọn kò gbójú lé Ẹni Mímọ́ Israẹli, wọn kò sì wádìí ọ̀rọ̀ lọ́dọ̀ OLUWA.
Pín
Kà Isa 31Isa 31:1 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ OLúWA.
Pín
Kà Isa 31