Isa 31

31
Ọlọrun Yóo Dáàbò Bo Jerusalẹmu
1EGBE ni fun awọn ti o sọkalẹ lọ si Egipti fun iranlọwọ; ti nwọn gbẹkẹlẹ ẹṣin, ti nwọn gbiyèle kẹkẹ́, nitoriti nwọn pọ̀: nwọn si gbẹkẹle ẹlẹṣin nitoriti nwọn li agbara jọjọ; ṣugbọn ti nwọn kò wò Ẹni-Mimọ Israeli, nwọn kò si wá Oluwa!
2Ṣugbọn on gbọ́n pẹlu, o si mu ibi wá, kì yio si dá ọ̀rọ rẹ̀ padà: on si dide si ile awọn oluṣe buburu, ati si oluranlọwọ awọn ti nṣiṣẹ aiṣedede.
3Nitori enia li awọn ara Egipti, nwọn kì iṣe Ọlọrun; ẹran li awọn ẹṣin wọn, nwọn kì si iṣe ẹmi. Oluwa yio si nà ọwọ́ rẹ̀, ki ẹniti nràn ni lọwọ ba le ṣubu, ati ki ẹniti a nràn lọwọ ba lè ṣubu, gbogbo wọn o jùmọ ṣegbe.
4Nitori bayi li Oluwa ti wi fun mi pe, Gẹgẹ bi kiniun ati ẹgbọ̀rọ kiniun ti nkùn si ohun-ọdẹ rẹ̀, nigbati a npè ọpọlọpọ oluṣọ́-agutan jade wá si i, ti on kò bẹ̀ru ohùn wọn, ti kò si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ fun ariwo wọn: bẹ̃li Oluwa awọn ọmọ-ogun yio sọkalẹ wá lati jà lori okè-nla Sioni, ati lori oke kékèké rẹ̀.
5Gẹgẹ bi ẹiyẹ iti fi iyẹ́ apa ṣe, bẹ̃ni Oluwa awọn ọmọ-ogun yio dabòbo Jerusalemu; ni didãbòbo o pẹlu yio si gbà o silẹ; ni rirekọja on o si dá a si.
6Ẹ yipadà si ẹniti ẹ ti nṣọ̀tẹ si gidigidi, ẹnyin ọmọ Israeli.
7Nitori li ọjọ na ni olukuluku enia yio jù ere fadaka rẹ̀, ati ere wura rẹ̀ nù, ti ọwọ́ ẹnyin tikara nyin ti ṣe fun ẹ̀ṣẹ fun nyin.
8Nigbana ni ara Assiria na yio ṣubú nipa idà, ti kì iṣe nipa idà ọkunrin, ati idà, ti ki iṣe ti enia yio jẹ ẹ: ṣugbọn on o sá kuro niwaju idà, awọn ọdọmọkunrin rẹ̀ yio ma sìnrú.
9Apata rẹ̀ yio kọja lọ fun ẹ̀ru, awọn olori rẹ̀ yiọ bẹ̀ru asia na, ni Oluwa wi, ẹniti iná rẹ̀ wà ni Sioni, ati ileru rẹ̀ ni Jerusalemu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isa 31: YBCV

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀

YouVersion nlo awọn kuki lati ṣe adani iriri rẹ. Nipa lilo oju opo wẹẹbu wa, o gba lilo awọn kuki wa gẹgẹbi a ti ṣalaye ninu Eto Afihan wa