Isaiah 31

31
Ègbé ni fún àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé Ejibiti
1Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí
Ejibiti fún ìrànlọ́wọ́,
tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin
tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn
àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn,
ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ Israẹli n nì,
tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa.
2Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá;
òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ.
Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà,
àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.
3Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará Ejibiti
wọn kì í ṣe Ọlọ́run;
ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí.
Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde,
ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀,
ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú;
àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun.
4Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi:
“Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké
àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀
bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn
tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀,
ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn
akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá
láti jagun lórí òkè Sioni àti lórí ibi gíga rẹ̀.
5Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè
Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo Jerusalẹmu,
Òun yóò dáàbò bò ó yóò sì tú u sílẹ̀
Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.”
6Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, Ẹ̀yin ọmọ Israẹli.
7Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe.
8“Asiria yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá;
idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n.
Wọn yóò sì sá níwájú idà náà
àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe.
9Àpáta rẹ yóò kọjá lọ fún ẹ̀rù;
àwọn olórí rẹ yóò bẹ̀rù asia náà,”
ni Olúwa wí,
ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní Sioni,
ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní Jerusalẹmu.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Isaiah 31: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀