Isa 2:1-4
Isa 2:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ ti Isaiah ọmọ Amosi ri nipa Juda ati Jerusalemu. Yio si ṣe ni ọjọ ikẹhìn, a o fi òke ile Oluwa kalẹ lori awọn òke nla, a o si gbe e ga ju awọn òke kékèké lọ; gbogbo orilẹ-ède ni yio si wọ́ si inu rẹ̀. Ọ̀pọlọpọ enia ni yio si lọ, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si òke Oluwa, si ile Ọlọrun Jakobu; On o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa rẹ̀; nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu. On o si dajọ lãrin awọn orilẹ-ède, yio si ba ọ̀pọlọpọ enia wi: nwọn o fi idà wọn rọ ọbẹ-plau, nwọn o si fi ọ̀kọ wọn rọ dojé; orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède; bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ.
Isa 2:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ọ̀rọ̀ tí Aisaya ọmọ Amosi sọ nípa Juda ati Jerusalẹmu nìyí: Ní ọjọ́ iwájú òkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ, a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ. Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ. Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé: “Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ, kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀, kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wá ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.” Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè; yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí. Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́, wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́, wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.
Isa 2:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Èyí ni ohun tí Isaiah ọmọ Amosi rí nípa Juda àti Jerusalẹmu: Ní ìgbẹ̀yìn ọjọ́ òkè tẹmpili OLúWA ni a ó fi ìdí rẹ̀ kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí olú nínú àwọn òkè, a ó sì gbé e ga ju àwọn òkè kéékèèkéé lọ, gbogbo orílẹ̀-èdè yóò sì máa sàn sínú un rẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni yóò wá, wọn yóò sì wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á gòkè ńlá OLúWA, àti sí ilé Ọlọ́run Jakọbu. Òun yóò kọ́ wa ní ọ̀nà rẹ̀, kí àwa kí ó lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.” Òfin yóò jáde láti Sioni wá, àti ọ̀rọ̀ OLúWA láti Jerusalẹmu. Òun ó ṣe ìdájọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, yóò sì parí aáwọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn. Wọn yóò fi idà wọn rọ ọkọ́ ìtulẹ̀, wọn yóò sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé. Orílẹ̀-èdè kì yóò sì gbé idà sí orílẹ̀-èdè mọ́, bẹ́ẹ̀ ní wọn kì yóò kọ́ ogun jíjà mọ́.