Isa 2
2
Alaafia Ayérayé
1Ọ̀RỌ ti Isaiah ọmọ Amosi ri nipa Juda ati Jerusalemu.
2Yio si ṣe ni ọjọ ikẹhìn, a o fi òke ile Oluwa kalẹ lori awọn òke nla, a o si gbe e ga ju awọn òke kékèké lọ; gbogbo orilẹ-ède ni yio si wọ́ si inu rẹ̀.
3Ọ̀pọlọpọ enia ni yio si lọ, nwọn o si wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si òke Oluwa, si ile Ọlọrun Jakobu; On o si kọ́ wa li ọ̀na rẹ̀, awa o si ma rìn ni ipa rẹ̀; nitori lati Sioni ni ofin yio ti jade lọ, ati ọ̀rọ Oluwa lati Jerusalemu.
4On o si dajọ lãrin awọn orilẹ-ède, yio si ba ọ̀pọlọpọ enia wi: nwọn o fi idà wọn rọ ọbẹ-plau, nwọn o si fi ọ̀kọ wọn rọ dojé; orilẹ-ède kì yio gbe idà soke si orilẹ-ède; bẹ̃ni nwọn kì yio kọ́ ogun jijà mọ.
5Ara ile Jakobu, ẹ wá, ẹ jẹ́ ka rìn ninu imọlẹ Ọluwa.
A óo pa Ìgbéraga Run
6Nitorina ni iwọ ṣe kọ̀ awọn enia rẹ, ile Jakobu silẹ̀; nitoriti nwọn kún lati ìla ọ̀run wá, nwọn jẹ alafọ̀ṣẹ bi awọn ara Filistia, nwọn si nṣe inu didùn ninu awọn ọmọ alejò.
7Ilẹ wọn pẹlu kún fun fadakà ati wurà; bẹ̃ni kò si opin fun iṣura wọn; ilẹ wọn si kun fun ẹṣin, bẹ̃ni kò si opin fun kẹkẹ́ ogun wọn.
8Ilẹ wọn kún fun oriṣa pẹlu; nwọn mbọ iṣẹ ọwọ́ ara wọn, eyiti ika awọn tikalawọn ti ṣe.
9Enia lasan si foribalẹ, ẹni-nla si rẹ̀ ara rẹ̀ silẹ; nitorina má ṣe darijì wọn.
10Wọ̀ inu apata lọ, ki o si fi ara rẹ pamọ ninu ekuru, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀.
11A o rẹ̀ ìwo giga enia silẹ, a o si tẹ̀ ori igberaga enia ba, Oluwa nikanṣoṣo li a o gbe ga li ọjọ na.
12Nitori ọjọ Oluwa awọn ọmọ-ogun yio wà lori olukuluku ẹniti o rera, ti o si gberaga, ati lori olukuluku ẹniti a gbe soke, on li a o si rẹ̀ silẹ.
13Lori gbogbo igi kedari Lebanoni, ti o ga, ti a sì gbe soke, ati lori gbogbo igi-nla Baṣani.
14Ati lori gbogbo òke giga, ati lori gbogbo òke kékèké ti a gbe soke.
15Ati lori gbogbo ile-iṣọ giga ati lori gbogbo odi,
16Ati lori gbogbo ọkọ̀ Tarṣiṣi, ati lori gbogbo awòran ti o wuni,
17A o si tẹ̀ ori igberaga enia balẹ, irera awọn enia li a o si rẹ̀ silẹ; Oluwa nikanṣoṣo li a o gbega li ọjọ na.
18Awọn òriṣa ni yio si parun patapata.
19Nwọn o si wọ̀ inu ihò apata lọ, ati inu ihò ilẹ, nitori ìbẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀, nigbati o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji.
20Li ọjọ na, enia yio jù òriṣa fadakà rẹ̀, ati òriṣa wurà rẹ̀, ti nwọn ṣe olukuluku wọn lati ma bọ, si ekute ati si àdan,
21Lati lọ sinu pàlapala apata, ati soke apata sisán, nitori ibẹru Oluwa, ati nitori ogo ọlanla rẹ̀; nigbati o ba dide lati mì ilẹ aiye kijikiji.
22Ẹ simi lẹhìn enia, ẹmi ẹniti o wà ni ihò imu rẹ̀; nitori ninu kini a le kà a si?
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
Isa 2: YBCV
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Yoruba Bible Crowther Version © The Bible Society of Nigeria, 2012.