AISAYA 2

2
Alaafia Ayérayé
(Mika 4:1-3)
1Ọ̀rọ̀ tí Aisaya ọmọ Amosi sọ nípa Juda ati Jerusalẹmu nìyí:
2Ní ọjọ́ iwájú
òkè ilé OLUWA yóo fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òkè tí ó ga jùlọ,
a óo sì gbé e ga ju àwọn òkè yòókù lọ.
Gbogbo orílẹ̀-èdè yóo wá sibẹ.
3Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé:
“Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ,
kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,
kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀,
kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wá
ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.”
4Yóo ṣe ìdájọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè;#Joẹl 3:10; Mika 4:3
yóo sì bá ọpọlọpọ eniyan wí.
Wọn yóo fi idà wọn rọ ọkọ́,
wọn yóo sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ dòjé.
Àwọn orílẹ̀-èdè kò ní yọ idà sí ara wọn mọ́,
wọn kò sì ní kọ́ ogun jíjà mọ́.
5Ẹ̀yin ìdílé Jakọbu
ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á rìn ninu ìmọ́lẹ̀ OLUWA.
A óo pa Ìgbéraga Run.
6Nítorí o ti ta àwọn eniyan rẹ nù,
àní, ìdílé Jakọbu.
Nítorí pé àwọn aláfọ̀ṣẹ ará ìhà ìlà oòrùn pọ̀ láàrin wọn,
àwọn alásọtẹ́lẹ̀ sì pọ̀ bíi ti àwọn ará Filistini,
Wọ́n ti gba àṣà àwọn àjèjì.
7Wúrà ati fadaka kún ilẹ̀ wọn,
ìṣúra wọn kò sì lópin.
Ẹṣin kún ilẹ̀ wọn,
kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò sì lóǹkà.
8Ilẹ̀ wọn kún fún oriṣa,
wọ́n ń bọ iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn,
wọ́n ń wólẹ̀ fún ohun tí wọ́n fọwọ́ ara wọn ṣe.
9Bẹ́ẹ̀ ni eniyan ṣe tẹ ara rẹ̀ lórí ba
tí ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀.
Oluwa, máṣe dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n.
10Ẹ wọnú àpáta lọ,#Ifi 6:15; 2 Tẹs 1:9
kí ẹ sì farapamọ́ sinu ilẹ̀.
Ẹ sá fún ibinu OLUWA
ati ògo ọlá ńlá rẹ̀.
11A óo rẹ ọlọ́kàn gíga eniyan sílẹ̀,
a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀;
OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà.
12Nítorí OLUWA àwọn ọmọ ogun ti ya ọjọ́ kan sọ́tọ̀,
tí yóo dojú ìjà kọ àwọn agbéraga,
ati àwọn ọlọ́kàn gíga,
ati gbogbo nǹkan tí à ń gbéga.
13Yóo dojú kọ gbogbo igi Kedari ti Lẹbanoni,
tí ó ga fíofío, ati gbogbo igi oaku ilẹ̀ Baṣani;
14ati gbogbo àwọn òkè ńláńlá,
ati gbogbo òkè gíga,
15ati gbogbo ilé-ìṣọ́ gíga
ati gbogbo odi tí ó lágbára,
16ati gbogbo ọkọ̀ ojú omi láti ìlú Taṣiṣi,
ati gbogbo ọkọ̀ tí ó dára.
17Àwọn ọlọ́kàn gíga yóo di ẹni ilẹ̀,
a óo sì rẹ àwọn onigbeeraga sílẹ̀.
OLUWA nìkan ni a óo gbéga ní ọjọ́ náà,
18àwọn oriṣa yóo sì pòórá patapata.
19Àwọn eniyan yóo sá sinu ihò àpáta,
wọn yóo sì wọ inú ihò ilẹ̀ lọ,
nígbà tí wọ́n bá ń sá fún ibinu OLUWA,
ati ògo ọlá ńlá rẹ̀
nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
20Ní ọjọ́ náà,
àwọn eniyan óo kó àwọn ère fadaka wọn dànù,
ati àwọn ère wúrà tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe, tí wọn tún ń bọ.
Wọn yóo dà wọ́n fún àwọn èkúté ati àwọn àdán.
21Wọn óo wọ inú pàlàpálá àpáta,
ati inú ihò àwọn òkè gíga;
nígbà tí wọn bá ń sá fún ibinu OLUWA,
ati ògo ọlá ńlá rẹ̀,
nígbà tí ó bá dìde láti mi ayé tìtì.
22Ẹ má gbẹ́kẹ̀lé eniyan mọ́.
Ẹlẹ́mìí ni òun alára,
nítorí pé kí ni ó lè ṣe?

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

AISAYA 2: YCE

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀