Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé:
“Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ,
kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu,
kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀,
kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀.
Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wá
ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.”