Hos 9:1-2
Hos 9:1-2 Bibeli Mimọ (YBCV)
MÁṢE yọ̀, Israeli, fun ayọ̀, bi awọn enia miràn: nitori iwọ ti ṣe agbère lọ kuro lọdọ Ọlọrun rẹ, iwọ ti fẹ́ èrè lori ilẹ ipakà gbogbo. Ilẹ ipakà ati ohun ifunti kì yio bọ́ wọn, ọti-waini titun yio si tan ninu rẹ̀.
Hos 9:1-2 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ má yọ̀, ẹ sì má dá ara yín ninu dùn, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nítorí ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, ẹ ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ sọ́dọ̀ oriṣa. Inú yín ń dùn sí owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ibi ìpakà yín. Ọkà ibi ìpakà yín ati ọtí ibi ìpọntí yín kò ní to yín, kò sì ní sí waini tuntun mọ́.
Hos 9:1-2 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli; má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù. Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín. Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà. Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀