Hosea 9

9
Ìdájọ́ fún ẹsẹ̀ Israẹli
1Má ṣe yọ̀, ìwọ Israẹli;
má ṣe hó ìhó ayọ̀ bí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù.
Nítorí ẹ ti jẹ́ aláìṣòótọ́ si Ọlọ́run yín.
Ẹ fẹ́ràn láti gba owó iṣẹ́ àgbèrè
ní gbogbo ilẹ̀ ìpakà.
2Àwọn ilẹ̀ ìpakà àti ilé ìfun wáìnì kò ní fún àwọn ènìyàn lóúnjẹ
wáìnì tuntun yóò tàn láìròtẹ́lẹ̀
3Wọn kò ní ṣẹ́kù sí ilé Olúwa
Efraimu yóò padà sí Ejibiti
Yóò sì jẹ oúnjẹ àìmọ́ ní Asiria.
4Wọn kò ní fi ọrẹ ohun mímu fún Olúwa.
Bẹ́ẹ̀ ni ìrúbọ wọn kò ní mú, inú rẹ̀ dùn.
Ìrú ẹbọ bẹ́ẹ̀ yóò dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀.
Gbogbo àwọn tó bá sì jẹ ẹ́ yóò di aláìmọ́.
Oúnjẹ yìí yóò wà fún wọn fúnrawọn
kò ní wá sí orí tẹmpili Olúwa.
5Kí ni ẹ̀yin ó ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yàn
ní àwọn ọjọ́ àjọ̀dún Olúwa?
6Bí wọ́n tilẹ̀ yọ́ kúrò lọ́wọ́ ìparun
Ejibiti yóò kó wọn jọ,
Memfisi yóò sì sin wọ́n.
Ibi ìsọjọ̀ fàdákà wọn ni ẹ̀gún yóò jogún,
Ẹ̀gún yóò bo àpótí ìṣúra fàdákà wọn.
Ẹ̀gún yóò sì bo
gbogbo àgọ́ wọn.
7 Àwọn ọjọ́ ìjìyà ń bọ̀;
àwọn ọjọ́ ìṣirò iṣẹ́ ti dé
Jẹ́ kí Israẹli mọ èyí
Nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ yín pọ̀
ìkórìíra yín sì pọ̀ gan an ni.
A ka àwọn wòlíì sí òmùgọ̀
A ka ẹni ìmísí sí asínwín.
8Wòlíì, papọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,
ni olùṣọ́ ọ Efraimu.
Síbẹ̀ ìdẹ̀kùn dúró dè é ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìkórìíra ní ilé Ọlọ́run rẹ̀
9Wọ́n ti gbilẹ̀ nínú ìwà ìbàjẹ́
gẹ́gẹ́ bí i ọjọ́ Gibeah
Ọlọ́run yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
10“Mo rí Israẹli bí èso àjàrà ní aginjù.
Mo rí àwọn baba yín,
bí àkọ́pọ́n nínú igi ọ̀pọ̀tọ́ ní àkọ́so rẹ̀.
Ṣùgbọ́n wọ́n tọ Baali-Peori lọ,
wọ́n yà wọn sọ́tọ̀ fún òrìṣà tó ń mú ìtìjú bá ni,
ohun ìríra wọn sì rí gẹ́gẹ́ bí wọn ti fẹ́. 11Ògo Efraimu yóò fò lọ bí ẹyẹ
kò ní sí ìfẹ́rakù, ìlóyún àti ìbímọ.
12Bí wọ́n tilẹ̀ tọ́ ọmọ dàgbà.
Èmi yóò mú wọn ṣọ̀fọ̀ lórí gbogbo wọn
Ègbé ni fún wọn,
nígbà tí mo yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn!
13Mo rí Efraimu bí ìlú Tire
tí a tẹ̀dó sí ibi dáradára
ṣùgbọ́n Efraimu yóò kó àwọn
ọmọ rẹ̀ jáde fún àwọn apànìyàn.”
14Fún wọn, Olúwa!
Kí ni ìwọ yóò fún wọn?
Fún wọn ní inú tí ń ba oyún jẹ́
àti ọyàn gbígbẹ.
15“Nítorí gbogbo ìwà búburú tí wọ́n hù ní Gilgali
Mo kórìíra wọn níbẹ̀,
nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò lé wọn jáde ní ilé mi
Èmi kò ní ní ìfẹ́ wọn mọ́
ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo olórí wọn.
16Efraimu ti rẹ̀ dànù
gbogbo rẹ̀ sì ti rọ,
kò sì so èso,
Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ.
Èmi ó pa àwọn ọmọ wọn tí wọ́n fẹ́ràn jùlọ.”
17Ọlọ́run mi yóò kọ̀ wọ́n sílẹ̀
nítorí pé wọn kò gbọ́rọ̀ sí i;
wọn yóò sì di alárìnkiri láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hosea 9: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀