Hosea 8

8
Israẹli yípadà kúrò ní ọnà
1“Fi ìpè sí ẹnu rẹ!
Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa
nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú,
wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
2Israẹli kígbe pè mí
‘Háà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’
3Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀
ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀
4Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi
wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀.
Wọ́n fi fàdákà àti wúrà
ṣe ère fún ara wọn,
si ìparun ara wọn.
5Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria!
Ìbínú mi ń ru sí wọn:
yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?
6Israẹli ni wọ́n ti wá!
Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe é
Àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.
7“Wọ́n gbin afẹ́fẹ́
wọ́n sì ká ìjì
Igi ọkà kò lórí,
kò sì ní mú oúnjẹ wá.
Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà
àwọn àjèjì ni yóò jẹ.
8A ti gbé Israẹli mì,
báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
bí ohun èlò tí kò wúlò.
9Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri.
Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.
10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín orílẹ̀-èdè
Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí
Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù
lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.
11“Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀
gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn.
Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì
13Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi,
wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀
Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.
Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Wọn yóò padà sí Ejibiti
14 Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀
Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀
Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀
ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan
sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”

Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:

Hosea 8: YCB

Ìsàmì-sí

Pín

Daako

None

Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀