HOSIA 9
9
Hosia Kéde Ìjìyà fún Israẹli
1Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ má yọ̀, ẹ sì má dá ara yín ninu dùn, bí àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn, nítorí ẹ ti kọ Ọlọrun yín sílẹ̀, ẹ ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn lọ sọ́dọ̀ oriṣa. Inú yín ń dùn sí owó iṣẹ́ àgbèrè ní gbogbo ibi ìpakà yín. 2Ọkà ibi ìpakà yín ati ọtí ibi ìpọntí yín kò ní to yín, kò sì ní sí waini tuntun mọ́. 3Àwọn ọmọ Israẹli kò ní dúró ní ilẹ̀ OLUWA mọ́; Efuraimu yóo pada sí Ijipti, wọn yóo sì jẹ ohun àìmọ́ ní ilẹ̀ Asiria. 4Wọn kò ní rú ẹbọ ohun mímu sí OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni ẹbọ wọn kò ní tẹ́ ẹ lọ́rùn. Oúnjẹ wọn yóo dàbí oúnjẹ àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, àwọn tí wọ́n bá jẹ ninu rẹ̀ yóo di aláìmọ́. Ebi nìkan ni oúnjẹ wọn yóo wà fún, wọn kò ní mú wá fi rúbọ lára rẹ̀ ní ilé OLUWA. 5Kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àjọ̀dún tí a yà sọ́tọ̀, kí ni wọn óo ṣe ní ọjọ́ àsè OLUWA? 6Wọn yóo fọ́nká lọ sí Asiria; Ijipti ni yóo gbá wọn jọ, Memfisi ni wọn yóo sin wọ́n sí, Ẹ̀gún ọ̀gàn ni yóo hù bo àwọn nǹkan èlò fadaka olówó iyebíye wọn, ẹ̀gún yóo sì hù ninu àgọ́ wọn.
7Àkókò ìjìyà ati ẹ̀san ti dé, Israẹli yóo sì mọ̀. Ẹ̀ ń wí pé, “Òmùgọ̀ ni wolii, aṣiwèrè sì ni ẹni tí ó wà ninu ẹ̀mí,” nítorí ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yín, ati ìkórìíra yín tí ó pọ̀.#Luk 21:22 8Wolii ni aṣọ́nà fún Efuraimu, àwọn eniyan Ọlọrun mi, sibẹsibẹ tàkúté àwọn pẹyẹpẹyẹ wà lójú gbogbo ọ̀nà rẹ̀, ìkórìíra sì wà ní ilé Ọlọrun rẹ̀. 9Wọ́n ti sọ ara wọn di aláìmọ́ lọpọlọpọ, bí ìgbà tí wọ́n wà ní Gibea. Ọlọrun yóo ranti àìdára tí wọ́n ṣe, yóo sì jẹ wọ́n níyà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.#A. Ada 19:1-30
Ẹ̀ṣẹ̀ ati Ìjìyà Israẹli
10OLUWA wí pé: “Mo rí Israẹli he bí ìgbà tí eniyan rí èso àjàrà he ninu aṣálẹ̀. Lójú mi, àwọn baba ńlá yín dàbí èso tí igi ọ̀pọ̀tọ́ kọ́ so ní àkókò àkọ́so rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n rí sí mi, ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé òkè Baali Peori, wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ fún oriṣa Baali, wọ́n sì di ohun ẹ̀gbin, bí oriṣa tí wọ́n fẹ́ràn.#Nọm 25:1-5 11Ògo Efuraimu yóo fò lọ bí ẹyẹ, wọn kò ní lóyún, wọn kò ní bímọ, bẹ́ẹ̀ ni ọlẹ̀ kò ní sọ ninu wọn! 12Bí wọ́n bá tilẹ̀ bímọ, n óo pa wọ́n tí kò ní ku ẹyọ kan. Bí mo bá kọ̀ wọ́n sílẹ̀, wọ́n gbé!”
13Mo rí àwọn ọmọ Efuraimu bí ẹran àpajẹ; Efuraimu gbọdọ̀ kó àwọn ọmọ rẹ̀ jáde fún pípa. 14Fún wọn ní nǹkankan, OLUWA, OLUWA, kí ni ò bá tilẹ̀ fún wọn? Jẹ́ kí oyún máa bàjẹ́ lára obinrin wọn, kí ọmú wọn sì gbẹ.
Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Israẹli
15OLUWA ní, “Gbogbo ìwà burúkú wọn wà ní Giligali, ibẹ̀ ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí kórìíra wọn. Nítorí iṣẹ́ burúkú wọn, n óo lé wọn jáde ní ilé mi. N kò ní fẹ́ràn wọn mọ́, ọlọ̀tẹ̀ ni gbogbo àwọn olórí wọn. 16Ìyà jẹ Efuraimu, gbòǹgbò wọn ti gbẹ, wọn kò sì ní so èso mọ́. Bí wọ́n tilẹ̀ bímọ, n óo pa àwọn ọmọ tí wọ́n fẹ́ràn.”
Wolii Sọ̀rọ̀ Nípa Israẹli
17Ọlọrun mi yóo pa wọ́n run, nítorí pé wọn kò fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀; wọn yóo di alárìnkiri láàrin àwọn orílẹ̀-èdè.
Àwon tá yàn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí:
HOSIA 9: YCE
Ìsàmì-sí
Pín
Daako
Ṣé o fẹ́ fi àwọn ohun pàtàkì pamọ́ sórí gbogbo àwọn ẹ̀rọ rẹ? Wọlé pẹ̀lú àkántì tuntun tàbí wọlé pẹ̀lú àkántì tí tẹ́lẹ̀
Bible Society of Nigeria © 1900/2010